II. A. Ọba 2:1-6
II. A. Ọba 2:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati Oluwa nfẹ lati fi ãjà gbé Elijah lọ si òke ọrun, ni Elijah ati Eliṣa lọ kuro ni Gilgali. Elijah si wi fun Eliṣa pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Beteli. Eliṣa si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn sọ̀kalẹ lọ si Beteli. Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Beteli jade tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́. Elijah si wi fun u pe, Eliṣa, emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitori ti Oluwa rán mi si Jeriko. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn de Jeriko. Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Jeriko tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si dahùn wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́. Elijah si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Jordani. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Awọn mejeji si jùmọ nlọ.
II. A. Ọba 2:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí àkókò tó fún OLUWA láti fi ààjà gbé Elija lọ sí ọ̀run, Elija ati Eliṣa kúrò ní Giligali. Elija sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí Bẹtẹli.” Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Bẹtẹli. Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Bẹtẹli tọ Eliṣa wá, wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?” Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.” Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín, nítorí pé OLUWA rán mi sí Jẹriko.” Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Jẹriko. Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Jẹriko tọ Eliṣa wá, wọ́n sì bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?” Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.” Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí odò Jọdani.” Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ ń lọ.
II. A. Ọba 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Ọlọ́run ń fẹ́ gbé Elijah lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Elijah àti Eliṣa wà ní ọ̀nà láti Gilgali. Elijah wí fún Eliṣa pé, “Dúró níbí; OLúWA rán mi lọ sí Beteli.” Ṣùgbọ́n Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé OLúWA wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beteli. Àwọn ọmọ wòlíì ní Beteli jáde wá sí ọ̀dọ̀ Eliṣa wọ́n sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ pé OLúWA yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?” “Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Eliṣa dáhùn “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” Nígbà náà Elijah sì wí fún un pé, “Dúró níbí, Eliṣa: OLúWA ti rán mi lọ sí Jeriko.” Ó sì dá a lóhùn pé, “Bí ó ti dájú pé OLúWA yè àti tí ìwọ náà yè, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Wọ́n sì jọ lọ sí Jeriko. Àwọn ọmọ wòlíì tí ó wà ní Jeriko sì gòkè tọ Eliṣa wá wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ wí pé OLúWA yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?” “Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Ó dá wọn lóhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀.” Nígbà náà Elijah wí fún un pé, “Dúró níbí; OLúWA rán mi lọ sí Jordani.” Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, OLúWA yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ.