II. A. Ọba 2:1-12
II. A. Ọba 2:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati Oluwa nfẹ lati fi ãjà gbé Elijah lọ si òke ọrun, ni Elijah ati Eliṣa lọ kuro ni Gilgali. Elijah si wi fun Eliṣa pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Beteli. Eliṣa si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn sọ̀kalẹ lọ si Beteli. Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Beteli jade tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́. Elijah si wi fun u pe, Eliṣa, emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitori ti Oluwa rán mi si Jeriko. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn de Jeriko. Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Jeriko tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si dahùn wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́. Elijah si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Jordani. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Awọn mejeji si jùmọ nlọ. Adọta ọkunrin ninu awọn ọmọ awọn woli si lọ, nwọn si duro lati wò lòkere rére: awọn mejeji si duro li ẹba Jordani. Elijah si mu agbáda rẹ̀, o si lọ́ ọ lù, o si lù omi na, o si pin wọn ni iyà sihin ati sọhun, bẹ̃ni awọn mejeji si kọja ni ilẹ gbigbẹ. O si ṣe, nigbati nwọn kọja tan, ni Elijah wi fun Eliṣa pe, Bère ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to gbà mi kuro lọwọ rẹ. Eliṣa si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ìlọ́po meji ẹmi rẹ ki o bà le mi. On si wipe, Iwọ bère ohun ti o ṣoro: ṣugbọn, bi iwọ ba ri mi nigbati a ba gbà mi kuro lọdọ rẹ, yio ri bẹ̃ fun ọ; ṣugbọn bi bẹ̃ kọ, kì yio ri bẹ̃. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, ti nwọn nsọ̀rọ, si kiyesi i, kẹkẹ́ iná ati ẹṣin iná si là ãrin awọn mejeji; Elijah si ba ãjà gòke re ọrun. Eliṣa si ri i, o si kigbe pe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. On kò si ri i mọ: o si di aṣọ ara rẹ̀ mu, o si fà wọn ya si meji.
II. A. Ọba 2:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí àkókò tó fún OLUWA láti fi ààjà gbé Elija lọ sí ọ̀run, Elija ati Eliṣa kúrò ní Giligali. Elija sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí Bẹtẹli.” Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Bẹtẹli. Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Bẹtẹli tọ Eliṣa wá, wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?” Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.” Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín, nítorí pé OLUWA rán mi sí Jẹriko.” Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Jẹriko. Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Jẹriko tọ Eliṣa wá, wọ́n sì bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?” Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.” Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí odò Jọdani.” Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ ń lọ. Aadọta ninu àwọn ọmọ àwọn wolii náà sì dúró ní òkèèrè, wọ́n ń wò wọ́n. Elija ati Eliṣa sì dúró létí odò Jọdani. Elija bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó fi lu odò náà, odò sì pín sí meji títí tí Elija ati Eliṣa fi kọjá sí òdìkejì odò lórí ìyàngbẹ ilẹ̀. Níbẹ̀ ni Elija ti bèèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí á tó gbé mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Eliṣa sì dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìlọ́po meji agbára rẹ bà lé mi.” Elija dáhùn pé, “Ohun tí o bèèrè yìí ṣòro, ṣugbọn bí o bá rí mi nígbà tí wọ́n bá ń gbé mi lọ, o óo rí ohun tí o bèèrè gbà. Ṣugbọn bí o kò bá rí mi, o kò ní rí i gbà.” Bí wọ́n ti ń lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́-ogun iná ati ẹṣin iná gba ààrin wọn kọjá, Elija sì bá ààjà gòkè lọ sí ọ̀run. Bí Eliṣa ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó kígbe pe Elija, ó ní, “Baba mi, baba mi, kẹ̀kẹ́-ogun Israẹli ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” Kò rí Elija mọ́, ó bá fa aṣọ rẹ̀ ya sí meji láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.
II. A. Ọba 2:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Ọlọ́run ń fẹ́ gbé Elijah lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Elijah àti Eliṣa wà ní ọ̀nà láti Gilgali. Elijah wí fún Eliṣa pé, “Dúró níbí; OLúWA rán mi lọ sí Beteli.” Ṣùgbọ́n Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé OLúWA wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beteli. Àwọn ọmọ wòlíì ní Beteli jáde wá sí ọ̀dọ̀ Eliṣa wọ́n sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ pé OLúWA yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?” “Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Eliṣa dáhùn “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” Nígbà náà Elijah sì wí fún un pé, “Dúró níbí, Eliṣa: OLúWA ti rán mi lọ sí Jeriko.” Ó sì dá a lóhùn pé, “Bí ó ti dájú pé OLúWA yè àti tí ìwọ náà yè, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Wọ́n sì jọ lọ sí Jeriko. Àwọn ọmọ wòlíì tí ó wà ní Jeriko sì gòkè tọ Eliṣa wá wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ wí pé OLúWA yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?” “Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Ó dá wọn lóhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀.” Nígbà náà Elijah wí fún un pé, “Dúró níbí; OLúWA rán mi lọ sí Jordani.” Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, OLúWA yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ. Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jíjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Elijah àti Eliṣa ti dúró ní Jordani. Elijah sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀. Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí wọ́n rékọjá, Elijah sì wí fún Eliṣa pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?” “Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn. “Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Elijah wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹṣin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Elijah sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà. Eliṣa rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Israẹli!” Eliṣa kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.