II. A. Ọba 14:1-29
II. A. Ọba 14:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdun keji Joaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israeli ni Amasiah ọmọ Joaṣi jọba lori Juda. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on iṣe nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a si ma jẹ Jehoadani ti Jerusalemu. On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi Dafidi baba rẹ̀: o ṣe gẹgẹ bi ohun gbogbo ti Joaṣi baba rẹ̀ ti ṣe. Kiki a kò mu ibi giga wọnni kuro; sibẹ awọn enia nṣe irubọ, nwọn si nsun turari ni ibi giga wọnni. O si ṣe bi ijọba na ti fi idi mulẹ lọwọ rẹ̀ ni o pa awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o ti pa ọba baba rẹ̀. Ṣugbọn awọn ọmọ awọn apania na ni kò pa: gẹgẹ bi eyiti a ti kọ ninu iwe ofin Mose ninu eyiti Oluwa paṣẹ wipe, A kò gbọdọ pa baba fun ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa ọmọ fun baba; ṣugbọn olukuluku li a o pa fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀. On pa ẹgbãrun ninu awọn ara Edomu ni afonifojì iyọ, o si fi ogun kó Sela, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jokteeli titi di oni yi. Nigbana ni Amasiah rán ikọ̀ si Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israeli wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju. Jehoaṣi ọba Israeli si ranṣẹ si Amasiah ọba Juda, pe, Igi ẹgún ti mbẹ ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti mbẹ ni Lebanoni pe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ ọkunrin mi li aya: ẹranko igbẹ́ kan ti mbẹ ni Lebanoni kọja lọ, o si tẹ̀ igi ẹ̀gun na mọlẹ. Iwọ ti ṣẹgun Edomu nitõtọ, ọkàn rẹ si gbé ọ soke: mã ṣogo, ki o si gbe ile rẹ: nitori kini iwọ ṣe nfiràn si ifarapa rẹ, ki iwọ ki o lè ṣubu, iwọ, ati Juda pẹlu rẹ? Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́. Nitorina Jehoaṣi ọba Israeli gòke lọ; on ati Amasiah ọba Juda si wò ara wọn li oju ni Betṣemeṣi, ti iṣe ti Juda. A si le Juda niwaju Israeli; nwọn si sá olukuluku sinu agọ rẹ̀. Jehoaṣi ọba Israeli si mu Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi ọmọ Ahasiah ni Betṣemeṣi, o si wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu palẹ lati ẹnu bodè Efraimu titi de ẹnu bodè igun, irinwo igbọnwọ. O si kó gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun èlo ti a ri ninu ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, ati ògo, o si pada si Samaria. Ati iyokù iṣe Jehoaṣi ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, ati bi o ti ba Amasiah ọba Judah jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Jehoaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli; Jeroboamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda wà li ọdun mẹ̃dogun lẹhin ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israeli. Ati iyokù iṣe Amasiah, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Nwọn si dì rikiṣi si i ni Jerusalemu: o si salọ si Lakiṣi; ṣugbọn nwọn ranṣẹ tọ̀ ọ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ. Nwọn si gbé e wá lori ẹṣin: a si sin i ni Jerusalemu pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. Gbogbo awọn enia Juda si mu Asariah ẹni ọdun mẹrindilogun, nwọn si fi i jọba ni ipò Amasiah baba rẹ̀. On si kọ́ Elati, o si mu u pada fun Juda, lẹhin ti ọba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀. Li ọdun kẹ̃dogun Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli bẹ̀rẹ si ijọba ni Samaria, o si jọba li ọdun mọkanlelogoji. O si ṣe buburu li oju Oluwa: kò yà kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀. O si tun mu agbègbe ilẹ Israeli pada lati atiwọ̀ Hamati titi de okun pẹ̀tẹlẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti sọ nipa ọwọ iranṣẹ rẹ̀ Jona woli, ọmọ Amittai, ti Gat-heferi. Nitori Oluwa ri ipọnju Israeli pe, o korò gidigidi: nitori kò si ọmọ-ọdọ, tabi omnira tabi olurànlọwọ kan fun Israeli. Oluwa kò si wipe on o pa orukọ Israeli rẹ́ labẹ ọrun: ṣugbọn o gbà wọn nipa ọwọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi. Ati iyokù iṣe Jeroboamu ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, bi o ti jagun si, ati bi o ti gbà Damasku, ati Hamati, ti iṣe ti Juda, pada fun Israeli, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Jeroboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ani, pẹlu awọn ọba Israeli; Sakariah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
II. A. Ọba 14:1-29 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún keji tí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi jọba ní Israẹli ni Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Jehoadini, ará Jerusalẹmu, ni ìyá rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò dàbí ti Dafidi baba ńlá rẹ̀; ohun gbogbo tí Joaṣi baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run; àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń sun turari. Nígbà tí ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ tán, ó pa àwọn olórí ogun tí wọ́n pa baba rẹ̀. Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn nítorí pé òfin Mose pa á láṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba. Olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Amasaya pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó ṣẹgun Sela, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jokiteeli, orúkọ yìí ni ìlú náà ń jẹ́ títí di òní yìí. Lẹ́yìn náà, Amasaya ranṣẹ sí Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli, láti pè é níjà sí ogun. Ṣugbọn Jehoaṣi ọba ranṣẹ pada pẹlu òwe yìí: Ó ní, “Ní ìgbà kan ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún kan tí ó wà ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Fi ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi ní aya.’ Ṣugbọn ẹranko burúkú kan tí ó wà ní Lẹbanoni ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀. Nisinsinyii, ìwọ Amasaya, nítorí pé o ti ṣẹgun Edomu, ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga. Jẹ́ kí ògo rẹ yìí tẹ́ ọ lọ́rùn, kí ló dé tí o fi fẹ́ dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ sí ìparun ara rẹ ati ti Juda?” Ṣugbọn Amasaya kọ̀ kò gbọ́, nítorí náà, Jehoaṣi ọba Israẹli kó ogun lọ pàdé Amasaya ọba Juda ní Beti Ṣemeṣi tí ó wà ní Juda. Israẹli ṣẹgun Juda, gbogbo àwọn ọmọ ogun Juda sì pada sí ilé wọn. Ọwọ́ Jehoaṣi tẹ Amasaya, lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Igun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ irinwo igbọnwọ (400 mita). Ó kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí ati gbogbo àwọn ohun èlò ilé OLUWA ati gbogbo ohun tí ó níye lórí ní ààfin, ó sì pada sí Samaria. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe, ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya jà, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jehoaṣi kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Amasaya ọba, ọmọ Joaṣi gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọba Israẹli. Gbogbo nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amasaya Ọba ní Jerusalẹmu, ó sì sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n rán eniyan lọ bá a níbẹ̀, wọ́n sì pa á. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ sórí ẹṣin wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi. Àwọn eniyan Juda sì fi Asaraya, ọmọ rẹ̀, jọba. Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni, nígbà tí ó jọba. Asaraya tún ìlú Elati kọ́, ó sì dá a pada fún Juda lẹ́yìn ikú baba rẹ̀. Ní ọdún kẹẹdogun tí Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda ni Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli jọba ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkanlelogoji. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA; ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. Ó gba gbogbo ilẹ̀ Israẹli pada láti ẹnubodè Hamati títí dé Òkun Araba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ láti ẹnu wolii rẹ̀, Jona, ọmọ Amitai, ará Gati Heferi. OLUWA rí i pé ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli pọ̀, kò sì sí ẹni tí ìpọ́njú náà kò kàn, ati ẹrú ati ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò tíì sọ pé òun óo pa gbogbo Israẹli run, nítorí náà, ó ṣẹgun fún wọn láti ọwọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jeroboamu ṣe, ìwà akọni rẹ̀ lójú ogun ati bí ó ti gba Damasku ati Hamati, tí wọ́n jẹ́ ti Juda tẹ́lẹ̀ rí, fún Israẹli, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jeroboamu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba, Sakaraya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
II. A. Ọba 14:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kejì tí Jehoaṣi ọmọ Joahasi ọba Israẹli, Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba. Ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jehoadani; ó wá láti Jerusalẹmu. Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLúWA, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dafidi baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ baba a rẹ̀ Joaṣi. Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò; Àwọn ènìyàn sì tẹ̀síwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọingbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba. Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mose níbi tí OLúWA ti paláṣẹ pé: “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ará Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀, ó sì fi agbára mú Sela nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jokteeli, orúkọ tí ó ní títí di òní. Nígbà náà, Amasiah rán àwọn ìránṣẹ́ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu ọba Israẹli pẹ̀lú ìpèníjà: “Wá, jẹ́ kí á wo ara wa ní ojú.” Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì sí Amasiah ọba Juda: “Òṣùṣú kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí kedari ní Lebanoni, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó.’ Nígbà náà ẹranko ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin tinú igbó ní Lebanoni wá pẹ̀lú ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ òṣùṣú náà mọ́lẹ̀. Ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsin yìí ìwọ ṣe ìgbéraga. Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?” Bí ó ti wù kí ó rí Amasiah kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi ọba Israẹli sì dojúkọ ọ́. Òun àti Amasiah ọba Juda kọjú sí ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda. A kó ipa ọ̀nà Juda nípasẹ̀ Israẹli, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀. Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi, ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà, Jehoaṣi lọ sí Jerusalẹmu, ó sì lọ wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Efraimu sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà (600). Ó mú gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun tí ó rí nínú ilé tí a kọ́ fún OLúWA àti níbi ìfowópamọ́ sí nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn ògo, ó sì dá wọn padà sí Samaria. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jehoaṣi, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? Jehoaṣi sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sí Samaria pẹ̀lú àwọn ọba Israẹli. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli. Fún ti ìyókù iṣẹ́ rẹ̀ nígbà ìjọba Amasiah, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda? Wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi, ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀. Wọ́n gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin, a sì sin ín sí Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, ní ìlú ńlá ti Dafidi. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn Juda mú Asariah tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìn-dínlógún. Wọ́n sì ṣe é ní ọba ní ìrọ́pò baba rẹ̀ Amasiah. Òun ni ẹni tí ó tún Elati kọ́, ó sì dá a padà sí Juda lẹ́yìn tí Amasiah ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún tí Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ọba Israẹli di ọba ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún. Ó ṣe búburú ní ojú OLúWA kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati. Èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá. Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Israẹli padà láti Lebo-Hamati sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLúWA Ọlọ́run Israẹli, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jona ọmọ Amittai, wòlíì láti Gati-Heferi. OLúWA ti rí ìpọ́njú Israẹli pé, ó korò gidigidi, nítorí kò sí ẹrú tàbí òmìnira tàbí olùrànlọ́wọ́ kan fún Israẹli. Láti ìgbà tí OLúWA kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Israẹli láti abẹ́ ọ̀run. Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jeroboamu, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn agbára rẹ, bí ó ti jagun sí, àti bí ó ti gba Damasku àti Hamati, tí í ṣe ti Juda, padà fún Israẹli, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? Jeroboamu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àwọn ọba Israẹli Sekariah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.