II. A. Ọba 13:1-9

II. A. Ọba 13:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi, ọmọ Ahasaya, jọba ní Juda ni Jehoahasi, ọmọ Jehu, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ náà sílẹ̀. OLUWA bínú sí Israẹli, ó sì jẹ́ kí Hasaeli, ọba Siria, ati Benhadadi ọmọ rẹ̀ ṣẹgun Israẹli ní ọpọlọpọ ìgbà. Nígbà tí Jehoahasi gbadura sí OLUWA, tí OLUWA sì rí ìyà tí Hasaeli fi ń jẹ àwọn eniyan Israẹli, ó gbọ́ adura rẹ̀. (Nítorí náà, OLUWA rán olùgbàlà kan sí Israẹli láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Siria, ọkàn àwọn eniyan Israẹli sì balẹ̀ bíi ti ìgbà àtijọ́. Sibẹsibẹ wọn kò yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti mú Israẹli dá. Wọ́n sì tún ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kan náà, ère oriṣa Aṣera sì wà ní Samaria.) Jehoahasi kò ní àwọn ọmọ ogun mọ́ àfi aadọta ẹlẹ́ṣin, ati kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́wàá ati ẹgbaarun (10,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn. Ọba Siria ti pa gbogbo wọn run, ó lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi erùpẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoahasi ṣe ati agbára rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

II. A. Ọba 13:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọdún kẹtàlélógún ti Joaṣi ọmọ ọba Ahasiah ti Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tà-dínlógún. Ó ṣe búburú níwájú OLúWA nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú OLúWA ru sí àwọn ọmọ Israẹli, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hasaeli ọba Siria àti Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀. Nígbà náà Jehoahasi kígbe ó wá ojúrere OLúWA, OLúWA sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Siria ti ń ni Israẹli lára gidigidi. OLúWA pèsè Olùgbàlà fún Israẹli, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Siria. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, wọ́n tẹ̀síwájú nínú rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah sì wà síbẹ̀ ní Samaria pẹ̀lú. Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ-ogun Jehoahasi àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí ọba Siria ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà. Fún ti ìyókù ìṣe Jehoahasi fún ìgbà, tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? Jehoahasi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.