II. A. Ọba 1:6
II. A. Ọba 1:6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si wi fun u pe, Ọkunrin kan li o gòke lati pade wa, o si wi fun wa pe, Ẹ lọ, ẹ pada tọ̀ ọba ti o rán nyin, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni iwọ fi ranṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni? nitorina, iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú.
II. A. Ọba 1:6 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin kan pàdé wa lọ́nà, ó sì sọ fún wa pé, ‘Ẹ pada sọ́dọ̀ ọba tí ó ran yín, kí ẹ sì sọ fún un pé, “OLUWA ní, ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni o fi rán oníṣẹ́ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi? Nítorí náà o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, o óo kú ni.” ’ ”
II. A. Ọba 1:6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin kan wá láti pàdé wa, ó sì wí fún wa pé, ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ ọba tí ó rán an yín kí ẹ sì wí fún un pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni o fi ń rán àwọn ènìyàn láti lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni? Nítorí náà ìwọ kò ní fi orí ibùsùn tí ìwọ dùbúlẹ̀ lé sílẹ̀. Láìsí àní àní ìwọ yóò kùú!” ’ ”