II. A. Ọba 1:13
II. A. Ọba 1:13 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si tun rán olori-ogun ãdọta ekẹta pẹlu ãdọta rẹ̀. Olori-ogun ãdọta kẹta si gòke, o si wá, o si wolẹ lori ẽkún rẹ̀ niwaju Elijah, o si bẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Iwọ, enia Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ́, jẹ ki ẹmi mi ati ẹmi awọn ãdọta ọmọ-ọdọ rẹ wọnyi, ki o ṣọwọn li oju rẹ.
II. A. Ọba 1:13 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọba rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀. Ṣugbọn ó gòkè lọ sọ́dọ̀ Elija, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú fún mi ati fún àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi, kí o sì dá ẹ̀mí wa sí.
II. A. Ọba 1:13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin. Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Elijah. “Ènìyàn Ọlọ́run,” Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ!