II. Kor 7:2-4
II. Kor 7:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbà wa tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹni, a kò bà ẹnikẹni jẹ, a kò rẹ́ ẹnikẹni jẹ. Emi kò sọ eyi lati da nyin lẹbi: nitori mo ti wi ṣãjú pe, ẹnyin wà li ọkàn wa ki a le jumọ kú, ati ki a le jumọ wà lãye. Mo ni igboiya nla lati ba nyin sọ̀rọ, iṣogo mi lori nyin pọ̀, mo kun fun itunu, mo si nyọ̀ rekọja ninu gbogbo ipọnju wa.
II. Kor 7:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ fi wá sọ́kàn. A kò ṣẹ ẹnikẹ́ni. A kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́. A kò sì rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Kì í ṣe pé mò ń fi èyí ba yín wí. Nítorí, bí mo ti sọ ṣáájú, ẹ ṣe ọ̀wọ́n fún wa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí ó bá kan ti ikú, kí á jọ kú ni, bí ó bá sì jẹ́ ti ìyè, kí á jọ wà láàyè ni. Ọkàn mi balẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yín. Mò ń fi ọwọ́ yín sọ̀yà. Mò ti ní ìtùnú kíkún. Ninu gbogbo ìpọ́njú wa, mo ní ayọ̀ lọpọlọpọ.
II. Kor 7:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.