II. Kor 6:17-18
II. Kor 6:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin. Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi.
Pín
Kà II. Kor 6II. Kor 6:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí. Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́, kí n lè gbà yín. N óo jẹ́ baba fun yín, ẹ̀yin náà óo sì jẹ́ ọmọ fún mi, lọkunrin ati lobinrin yín. Èmi Oluwa Olodumare ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Pín
Kà II. Kor 6II. Kor 6:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, “Ẹ jáde kúrò láàrín wọn, kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀, ni Olúwa wí. Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́; Èmi ó sì gbà yín.” Àti, “Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín, Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi! ní Olúwa Olódùmarè wí.”
Pín
Kà II. Kor 6