II. Kor 13:5 - Compare All Versions
II. Kor 13:5 YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ mã wadi ara nyin, bi ẹnyin bá wà ninu igbagbọ́; ẹ mã dan ara nyin wò. Tabi ẹnyin tikaranyin kò mọ̀ ara nyin pe Jesu Kristi wà ninu nyin? afi bi ẹnyin ba jẹ awọn ti a tanù.
II. Kor 13:5 YCE (Yoruba Bible)
Ẹ yẹ ara yín wò bí ẹ bá ń gbé ìgbé-ayé ti igbagbọ. Ẹ yẹ ara yín wò. Àbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ̀ pé Kristi Jesu wà ninu yín? Àfi bí ẹ bá ti kùnà nígbà tí ẹ yẹ ara yín wò!
II. Kor 13:5 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù.