II. Kor 12:1-3,7
II. Kor 12:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI ko le ṣe aiṣogo bi kò tilẹ ṣe anfani. Nitori emi ó wá si iran ati iṣipaya Oluwa. Emi mọ̀ ọkunrin kan ninu Kristi ni ọdún mẹrinla sẹhin, (yala ninu ara ni, emi kò mọ̀; tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀; Ọlọrun ni o mọ): a gbé irú enia bẹ̃ lọ si ọ̀run kẹta. Emi si ti mọ̀ irú ọkunrin bẹ̃, (yala li ara ni, tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀: Ọlọrun mọ̀)
II. Kor 12:7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja.
II. Kor 12:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ó yẹ kí n fọ́nnu. Rere kan kò ti ibẹ̀ wá, sibẹ n óo sọ ti ìran ati ìfarahàn Oluwa. Mo mọ ọkunrin onigbagbọ kan ní ọdún mẹrinla sẹ́yìn. Bí ó wà ninu ara ni o, bí ó rí ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé ọkunrin yìí lọ sí ọ̀run kẹta. Mo mọ ọkunrin yìí, bí ninu ara ni o, bí lójú ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé e lọ sí Paradise níbi tí ó gbé gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é sọ, ọ̀rọ̀ àṣírí tí kò gbọdọ̀ jáde lẹ́nu eniyan.
KỌRINTI KEJI 12:7 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, kí n má baà ṣe ìgbéraga nípa àwọn ìfihàn tí ó ga pupọ wọnyi, a fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ẹ̀gún yìí jẹ́ iranṣẹ Satani, láti máa gún mi, kí n má baà gbéraga.
II. Kor 12:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi kò lè ṣàì ṣògo bí kò tilẹ̀ ṣe àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípáyà ti Olúwa fihàn mí. Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kristi ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ẹni náà lọ sí ọ̀run kẹta. Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀.