II. Kro 9:7-8
II. Kro 9:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún si ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro nigbagbogbo niwaju rẹ, ti o si ngbọ́ ọgbọ́n rẹ. Olubukún li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o fẹran rẹ lati gbé ọ ka ori itẹ́ rẹ̀ lati ṣe ọba fun Oluwa Ọlọrun rẹ: nitoriti Ọlọrun rẹ fẹran Israeli lati fi idi wọn kalẹ lailai, nitorina ni o ṣe fi ọ jọba lori wọn, lati ṣe idajọ ati otitọ.
II. Kro 9:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn iyawo rẹ ṣoríire. Àwọn òṣìṣẹ́ rẹ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ náà ṣoríire. Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó gbé ọ gorí oyè láti jọba ní orúkọ rẹ̀. Ó ní ìfẹ́ sí Israẹli, ó fẹ́ fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae; nítorí náà, ó fi ọ́ jọba lórí wọn, láti máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo.”
II. Kro 9:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwo ní dídùn inú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ! Ìyìn ló yẹ fún OLúWA Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún OLúWA Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”