II. Kro 7:13-14
II. Kro 7:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi mo ba sé ọrun ti kò ba si òjo, tabi bi emi ba paṣẹ fun eṣú lati jẹ ilẹ na run, tabi bi mo ba rán àjakalẹ-arun si ãrin awọn enia mi; Bi awọn enia mi ti a npè orukọ mi mọ́, ba rẹ̀ ara wọn silẹ, ti nwọn ba si gbadura, ti nwọn ba si wá oju mi, ti nwọn ba si yipada kuro ninu ọ̀na buburu wọn; nigbana ni emi o gbọ́ lati ọrun wá, emi o si dari ẹ̀ṣẹ wọn jì, emi o si wò ilẹ wọn sàn.
II. Kro 7:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí mo bá sé ojú ọ̀run, tí òjò kò bá rọ̀, tabi tí mo pàṣẹ fún eṣú láti ba oko jẹ́, tabi tí mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin àwọn eniyan mi, bí àwọn eniyan mi, tí à ń fi orúkọ mi pè, bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì wá ojurere mi, tí wọ́n bá yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú wọnyi; n óo gbọ́ láti ọ̀run, n óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n óo sì wo ilẹ̀ wọn sàn.
II. Kro 7:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma bá à sí òjò, tàbí láti pàṣẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín àwọn ènìyàn mi, tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn.