II. Kro 6:7-11
II. Kro 6:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ti wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli: Oluwa si sọ fun Dafidi baba mi pe, nitoriti o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile fun orukọ mi, iwọ ṣeun li eyiti o wà li ọkàn rẹ. Sibẹ iwọ kò gbọdọ kọ́ ile na; ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio jade ti inu rẹ wá ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi. Oluwa si ti mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ; emi si dide ni ipò Dafidi baba mi, a si gbé mi ka itẹ́ Israeli bi Oluwa ti ṣe ileri, emi si ti kọ́ ile na fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli. Ati ninu rẹ̀ ni mo fi apoti-ẹri na si, ninu eyiti majẹmu Oluwa wà, ti o ba awọn ọmọ Israeli dá.
II. Kro 6:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Ó wu Dafidi, baba mi, láti kọ́ ilé kan fún ìjọ́sìn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ṣugbọn OLUWA sọ fún baba mi pé nǹkan dáradára ni pé ó wù ú lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún òun Ọlọrun, ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé náà, ọmọ bíbí inú rẹ̀ ni yóo kọ́ ilé fún òun. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Mo ti wà ní ipò baba mi, mo ti gorí ìtẹ́ ọba Israẹli, bí OLUWA ti ṣèlérí, mo sì ti kọ́ tẹmpili fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Mo ti gbé àpótí ẹ̀rí sibẹ, inú rẹ̀ sì ni majẹmu tí OLUWA bá àwọn eniyan Israẹli dá wà.”
II. Kro 6:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Baba mi Dafidi ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili fún orúkọ OLúWA, àní Ọlọ́run Israẹli. Ṣùgbọ́n OLúWA sọ fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹmpili yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹmpili náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ: òun ni yóò kọ́ tẹmpili fún orúkọ mi.’ “OLúWA sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dafidi baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹmpili fún orúkọ OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti OLúWA bá àwọn Israẹli ènìyàn mi dá wà.”