II. Kro 34:12 - Compare All Versions

II. Kro 34:12 YBCV (Bibeli Mimọ)

Awọn ọkunrin na fi otitọ ṣiṣẹ na: awọn alabojuto wọn ni Jahati ati Obadiah, awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Merari; ati Sekariah ati Meṣullamu, ninu awọn ọmọ Kohati, lati mu iṣẹ lọ; ati gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o ni ọgbọ́n ohun-elo orin.

II. Kro 34:12 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́, láti darí wọn ní Jahati àti Obadiah, àwọn ọmọ Lefi láti Merari, àti Sekariah àti Meṣullamu, sọ̀kalẹ̀ láti Kohati àwọn ọmọ Lefi gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin.

II. Kro 34:12 YCE (Yoruba Bible)

Àwọn eniyan náà fi òtítọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣàkóso wọn ni: Jahati ati Ọbadaya, láti inú ìran Merari, ati Sakaraya ati Meṣulamu, láti inú ìran Kohati. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n mọ̀ nípa ohun èlò orin