II. Kro 34:10 - Compare All Versions

II. Kro 34:10 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nwọn si fi i le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto iṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi i fun awọn aṣiṣẹ ti nṣiṣẹ ile Oluwa, lati tun ile na ṣe

II. Kro 34:10 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nígbà náà ni wọn sì fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé OLúWA. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń túnṣe, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé OLúWA.

II. Kro 34:10 YCE (Yoruba Bible)

Wọ́n kó owó náà fún àwọn tí ń ṣe àbojútó iṣẹ́ náà. Àwọn ni wọ́n ń sanwó fún àwọn tí wọn ń tún ilé OLUWA ṣe.