II. Kro 22:9
II. Kro 22:9 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wá Ahasiah: nwọn si mu u, (on sa ti fi ara pamọ́ ni Samaria,) nwọn si mu u tọ̀ Jehu wá: nigbati nwọn si pa a tan, nwọn sìn i: nitori ti nwọn wipe, ọmọ Jehoṣafati ni, ẹniti o wá Oluwa tọkàntọkan rẹ̀. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ni ile Ahasiah ti o yẹ fun ijọba.
II. Kro 22:9 Yoruba Bible (YCE)
Ó wá Ahasaya káàkiri títí; ní Samaria níbi tí ó sá pamọ́ sí ni wọ́n ti rí i mú, wọ́n bá mú un tọ Jehu wá, ó sì pa á. Wọ́n sin òkú rẹ̀, nítorí wọ́n ní, “Ọmọ ọmọ Jehoṣafati, ẹni tí ó fi tọkàntọkàn gbọ́ ti OLUWA ni.” Ní àkókò yìí, kò sí ẹnikẹ́ni ninu ìdílé Ahasaya tí ó lágbára tó láti jọba ilẹ̀ Juda.
II. Kro 22:9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó lọ láti wá Ahasiah, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sápamọ́ ní Samaria. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jehu, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé “Ọmọkùnrin Jehoṣafati ni, ẹni tí ó wá OLúWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Ahasiah tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró.