II. Kro 22:8 - Compare All Versions

II. Kro 22:8 YBCV (Bibeli Mimọ)

O si ṣe nigbati Jehu nmu idajọ ṣẹ sori ile Ahabu, o si ri awọn ijoye Juda, ati awọn ọmọ awọn arakunrin Ahasiah, ti nṣe iranṣẹ fun Ahasiah, o si pa wọn.

II. Kro 22:8 YCE (Yoruba Bible)

Nígbà tí Jehu dé láti pa ilé Ahabu run bí Ọlọrun ti fún un láṣẹ, ó pàdé àwọn ìjòyè Juda ati ọmọ arakunrin Ahasaya tí ó bá Ahasaya wá, ó bá pa wọ́n.

II. Kro 22:8 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nígbà tí Jehu ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Ahabu, ó rí àwọn ọmọbìnrin ọba ti Juda àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Ahasi, tí ó ń tọ́jú Ahasiah, ó sì pa wọ́n.