II. Kro 22:7-9
II. Kro 22:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iparun Ahasiah lati ọwọ Ọlọrun wá ni, nipa wiwá sọdọ Jehoramu: nigbati o si de, o si ba Jehoramu jade tọ̀ Jehu, ọmọ Nimṣi, ẹniti Oluwa fi ororo yàn lati ké ile Ahabu kuro. O si ṣe nigbati Jehu nmu idajọ ṣẹ sori ile Ahabu, o si ri awọn ijoye Juda, ati awọn ọmọ awọn arakunrin Ahasiah, ti nṣe iranṣẹ fun Ahasiah, o si pa wọn. O si wá Ahasiah: nwọn si mu u, (on sa ti fi ara pamọ́ ni Samaria,) nwọn si mu u tọ̀ Jehu wá: nigbati nwọn si pa a tan, nwọn sìn i: nitori ti nwọn wipe, ọmọ Jehoṣafati ni, ẹniti o wá Oluwa tọkàntọkan rẹ̀. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ni ile Ahasiah ti o yẹ fun ijọba.
II. Kro 22:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun ti pinnu pé ìparun óo bá Ahasaya nígbà tí ó bá lọ bẹ Joramu wò. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, òun pẹlu Joramu lọ pàdé Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí OLUWA ti yàn pé òun ni yóo pa ìdílé Ahabu run. Nígbà tí Jehu dé láti pa ilé Ahabu run bí Ọlọrun ti fún un láṣẹ, ó pàdé àwọn ìjòyè Juda ati ọmọ arakunrin Ahasaya tí ó bá Ahasaya wá, ó bá pa wọ́n. Ó wá Ahasaya káàkiri títí; ní Samaria níbi tí ó sá pamọ́ sí ni wọ́n ti rí i mú, wọ́n bá mú un tọ Jehu wá, ó sì pa á. Wọ́n sin òkú rẹ̀, nítorí wọ́n ní, “Ọmọ ọmọ Jehoṣafati, ẹni tí ó fi tọkàntọkàn gbọ́ ti OLUWA ni.” Ní àkókò yìí, kò sí ẹnikẹ́ni ninu ìdílé Ahasaya tí ó lágbára tó láti jọba ilẹ̀ Juda.
II. Kro 22:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Ahasiah sí Joramu, Ọlọ́run mú ìṣubú Ahasiah wá. Nígbà tí Ahasiah dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jehoramu láti lọ bá Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí OLúWA ti fi ààmì òróró yàn láti pa ìdílé Ahabu run. Nígbà tí Jehu ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Ahabu, ó rí àwọn ọmọbìnrin ọba ti Juda àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Ahasi, tí ó ń tọ́jú Ahasiah, ó sì pa wọ́n. Ó lọ láti wá Ahasiah, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sápamọ́ ní Samaria. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jehu, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé “Ọmọkùnrin Jehoṣafati ni, ẹni tí ó wá OLúWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Ahasiah tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró.