II. Kro 21:1-3
II. Kro 21:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
JEHOṢAFATI si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Jehoramu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. O si ni awọn arakunrin, awọn ọmọ Jehoṣafati, Asariah, ati Jehieli, ati Sekariah, ati Asariah ati Mikaeli, ati Ṣefatiah: gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda. Baba wọn si bun wọn li ẹ̀bun pupọ, ni fadakà ati ni wura, ati ohun iyebiye, pẹlu ilu olodi ni Juda, ṣugbọn o fi ijọba fun Jehoramu: nitori on li akọbi.
II. Kro 21:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Jehoṣafati kú, wọ́n sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀ ninu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Jehoramu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Jehoramu ní arakunrin mẹfa, tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Jehoṣafati, orúkọ wọn ni, Asaraya, Jehieli, ati Sakaraya, Asaraya, Mikaeli ati Ṣefataya. Baba wọn fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn: fadaka, wúrà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye, pẹlu àwọn ìlú olódi ní Juda. Ṣugbọn Jehoramu ni ó fi ìjọba lé lọ́wọ́, nítorí pé òun ni àkọ́bí rẹ̀.
II. Kro 21:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà Jehoṣafati sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Àwọn arákùnrin Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jẹ́ Asariah, Jehieli, Sekariah. Asariahu, Mikaeli àti Ṣefatia. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jehoṣafati ọba Israẹli. Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Juda, Ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jehoramu nítorí òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin.