II. Kro 18:1-34

II. Kro 18:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

JEHOṢAFATI si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ, o si ba Ahabu dá ana. Lẹhin ọdun melokan, on sọ̀kalẹ tọ Ahabu lọ si Samaria. Ahabu si pa agutan ati malu fun u li ọ̀pọlọpọ ati fun awọn enia ti o pẹlu rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati ba a gòke lọ si Ramoti-Gileadi. Ahabu ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati ọba Juda pe, Iwọ o ha ba mi lọ si Ramoti-Gileadi bi? On si da a li ohùn wipe, Emi bi iwọ, ati enia mi bi enia rẹ; awa o pẹlu rẹ li ogun na. Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa loni. Nitorina ọba Israeli kó awọn woli jọ, irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki awa ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Gòke lọ; Ọlọrun yio si fi i le ọba lọwọ. Ṣugbọn Jehoṣafati wipe, kò si woli Oluwa nihin pẹlu, ti awa ìba bère lọwọ rẹ̀? Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan mbẹ sibẹ lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀: nitoriti kò jẹ sọ asọtẹlẹ rere si mi lai, bikòṣe ibi nigbagbogbo: eyini ni Mikaiah, ọmọ Imla. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba ki o má sọ bẹ̃. Ọba Israeli si pè ìwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah ọmọ Imla, ki o yara wá. Ati ọba Israeli, ati Jehoṣafati, ọba Juda joko, olukuluku lori itẹ rẹ̀, nwọn si wọ aṣọ igunwa wọn, nwọn si joko ni ita ẹnubọde Samaria; gbogbo awọn woli si nsọ asọtẹlẹ niwaju wọn. Sedekiah ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn awọn ara Siria titi iwọ o fi run wọn. Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe, Gòke lọ si Ramoti-Gileadi, iwọ o ṣe rere; Oluwa yio si fi i le ọba lọwọ. Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah si wi fun u pe, Kiye si i, awọn woli fi ẹnu kan sọ rere fun ọba: Njẹ emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọkan ninu ti wọn, ki o si sọ rere. Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ani, eyiti Ọlọrun mi ba wi li emi o sọ. Nigbati o si tọ̀ ọba wá, ọba sọ fun u pe, Mikaiah, ki awa ki o lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? O si wipe, Ẹ lọ, ẹnyin o si ṣe rere, a o si fi wọn le nyin lọwọ. Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bú ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikòṣe ọ̀rọ otitọ li orukọ Oluwa? On si wipe, Emi ri gbogbo Israeli fọnka kiri lori awọn òke, bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa: jẹ ki nwọn ki o pada, olukuluku si ile rẹ̀ li alafia. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò ti wi fun ọ pe: on kì isọtẹlẹ rere si mi, bikòṣe ibi? Mikaiah si wipe, Nitorina, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun ọrun duro lapa ọtún ati lapa òsi rẹ̀. Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ọba Israeli, ki o le gòke lọ ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ekini si sọ bayi, ekeji si sọ miran. Nigbana ni ẹmi na jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a. Oluwa si wi fun u pe, Bawo? On si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. Oluwa si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃ na. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ. Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana, sunmọ ọ, o si lù Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà kọja lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ. Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o wọ inu iyẹwu de inu iyẹwu lọ ifi ara rẹ pamọ́, Nigbana ni ọba Israeli wipe, Ẹ mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba. Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi, ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi ọnjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia. Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ọdọ mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo! Bẹ̃li ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, si gòke lọ si Ramoti-Gileadi. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ìja; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Bẹ̃li ọba Israeli si pa aṣọ dà: nwọn si lọ si oju ìja. Ṣugbọn ọba Siria ti paṣẹ fun awọn olori kẹkẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀, pe, Ẹ máṣe ba ewe tabi àgba jà, bikòṣe ọba Israeli nikan. O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ ri Jehoṣafati, ni nwọn wipe eyi li ọba Israeli, nitorina nwọn yi i ka lati ba a jà: ṣugbọn Jehoṣafati kigbe, Oluwa si ràn a lọwọ: Ọlọrun si yi wọn pada kuro lọdọ rẹ̀. O si ṣe, bi awọn olori kẹkẹ́ ti woye pe kì iṣe ọba Israeli, nwọn yipada kuro lẹhin rẹ̀. Ọkunrin kan si fa ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin, o si wi fun olutọju kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ rẹ pada, ki o mu mi jade kuro loju ìja; nitoriti mo gbọgbẹ́. Ija na si pọ̀ li ọjọ na: pẹlupẹlu ọba Israeli duro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ kọju si awọn ara Siria titi di aṣãlẹ: o si kú li akokò ìwọ õrun.

II. Kro 18:1-34 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Jehoṣafati ọba Juda di ọlọ́rọ̀ ati olókìkí, ó fẹ́ ọmọ Ahabu kí ó lè ní àjọṣepọ̀ pẹlu Ahabu. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Jehoṣafati lọ sí ìlú Samaria láti bẹ Ahabu wò. Láti dá Jehoṣafati lọ́lá pẹlu àwọn tí wọ́n bá a wá, Ahabu pa ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù fún àsè. Ó rọ Jehoṣafati láti bá òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi. Ahabu, ọba Israẹli bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé o óo bá mi lọ gbógun ti Ramoti Gileadi?” Jehoṣafati dáhùn pé, “Tìrẹ ni èmi ati àwọn eniyan mi, a óo bá ọ lọ jagun náà.” Ṣugbọn Jehoṣafati sọ fún ọba Israẹli pé, “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ná.” Nítorí náà, Ahabu pe gbogbo àwọn Wolii jọ, gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400). Ó bi wọ́n pé, “Ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má lọ?” Wọ́n dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, Ọlọrun yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.” Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè lọ́wọ́ Ahabu pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA mìíràn mọ́ tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” Ahabu dáhùn pé, “Ó ku ọ̀kan tí à ń pè ní Mikaya, ọmọ Imila tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ rere kan kò ti ẹnu rẹ̀ jáde sí mi rí, àfi kìkì burúkú.” Jehoṣafati dáhùn, ó ní, “Má sọ bẹ́ẹ̀.” Nítorí náà, Ahabu ọba pe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó lọ pe Mikaya wá kíákíá. Àwọn ọba mejeeji gúnwà lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà, ní àbáwọ bodè Samaria, gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. Ọ̀kan ninu àwọn wolii tí à ń pè ní Sedekaya, ọmọ Kenaana ṣe àwọn ìwo irin kan, ó sì sọ fún Ahabu pé, “OLUWA ní, pẹlu àwọn ìwo wọnyi ni o óo fi bi àwọn ará Siria sẹ́yìn, títí tí o óo fi run wọ́n patapata.” Àwọn wolii yòókù ń sọ bákan náà, wọ́n ń wí pé, “Lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, o óo ṣẹgun. OLUWA yóo fi wọ́n lé ọba lọ́wọ́.” Iranṣẹ tí ó lọ pe Mikaya sọ fún un pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ni gbogbo àwọn wolii ń sọ, pé ọba yóo ṣẹgun, ìwọ náà sọ bẹ́ẹ̀.” Ṣugbọn Mikaya dáhùn pé, “Mo fi orúkọ OLUWA búra pé ohun tí Ọlọrun bá sọ fún mi pé kí n sọ ni n óo sọ.” Nígbà tí ó dé iwájú Ahabu, Ahabu bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má ṣe lọ?” Mikaya dáhùn pé, “Ẹ lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣẹgun.” Ṣugbọn Ahabu bi í pé, “Ìgbà mélòó ni mo níláti mú ọ búra pé kí o máa sọ òtítọ́ fún mi ní orúkọ OLUWA?” Mikaya bá sọ pé, “Mo rí i tí gbogbo ọmọ ogun Israẹli fọ́n káàkiri lórí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA bá sọ pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí. Jẹ́ kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀ ní alaafia.’ ” Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣé o ranti pé mo ti sọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún mi rí? Àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nìkan ni òun máa ń sọ.” Mikaya bá dáhùn pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! Mo rí OLUWA, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, àwọn ogun ọ̀run sì wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì rẹ̀. OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu, ọba Israẹli, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi, kí ó sì kú níbẹ̀.’ Bí àwọn kan tí ń sọ nǹkankan, ni àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà náà ni ẹ̀mí kan jáde, ó sì dúró níwájú OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tan Ahabu jẹ.’ OLUWA bá bèèrè pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o fẹ́ dá?’ Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo lọ sọ gbogbo àwọn wolii Ahabu di wolii èké.’ OLUWA bá dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ ni kí o lọ tàn án jẹ, o óo sì ṣe àṣeyọrí, lọ ṣe bí o ti wí.’ ” Mikaya ní, “OLUWA ni ó mú kí àwọn wolii rẹ wọnyi máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, ṣugbọn àjálù burúkú ni OLUWA ti pinnu pé yóo dé bá ọ.” Nígbà náà ni Sedekaya, ọmọ Kenaana súnmọ́ Mikaya, ó gbá a létí, ó wí pé, “Nígbà wo ni ẹ̀mí OLUWA fi mí sílẹ̀ tí ó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀?” Mikaya dáhùn pé, “Ojú rẹ yóo já a ní ọjọ́ náà, nígbà tí o bá lọ sá pamọ́ sí kọ̀rọ̀ yàrá.” Nígbà náà ni Ahabu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n mú Mikaya lọ sọ́dọ̀ Amoni, gomina ìlú ati sọ́dọ̀ Joaṣi, ọmọ ọba, kí wọ́n sì sọ fún wọn pé: Ẹ ju ọkunrin yìí sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì máa fún un ní omi ati burẹdi nìkan títí òun óo fi pada dé ní alaafia. Mikaya dáhùn pé, “Tí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún sọ siwaju sí i pé, kí olukuluku fetí sí ohun tí òun wí dáradára. Ahabu ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda lọ gbógun ti Ramoti Gileadi. Ahabu sọ fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sógun yìí, n óo yí ara pada. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Ọba Israẹli bá yíra pada, ó lọ sí ojú ogun. Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀gágun tí wọn ń ṣàkóso àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà bíkòṣe ọba Israẹli nìkan. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati, wọ́n rò pé ọba Israẹli ni, wọ́n bá yíjú sí i láti bá a jà. Jehoṣafati bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, OLUWA sì gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Nígbà tí àwọn ọ̀gágun náà rí i pé kì í ṣe Ahabu, ọba Israẹli, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀. Ṣugbọn ọmọ ogun Siria kan déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí ìgbàyà ati ihamọra rẹ̀ ti pàdé. Ó bá kígbe sí ẹni tí ó ru ihamọra rẹ̀ pé, “Mo ti fara gbọgbẹ́, yipada kí o gbé mi kúrò lójú ogun.” Ogun gbóná ní ọjọ́ náà, Ahabu ọba bá rá pálá dìde dúró, wọ́n fi ọwọ́ mú un ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó kọjú sí ogun Siria. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, ó kú.

II. Kro 18:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nísinsin yìí Jehoṣafati sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Ahabu nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Ahabu lálejò ní Samaria. Ahabu sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramoti Gileadi. Ahabu ọba Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jehoṣafati, ọba Juda pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Ramoti Gileadi?” Jehoṣafati sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ nínú ogun naà”. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati náà sì tún wí fún ọba Israẹli pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ OLúWA.” Bẹ́ẹ̀ ọba Israẹli kó àwọn wòlíì papọ̀, irínwó (4,000) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Ramoti Gileadi tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?” “Lọ,” wọ́n dáhùn, “nítorí tí Ọlọ́run yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n Jehoṣafati béèrè pé, “Ṣé kò ha sí wòlíì OLúWA níbí ẹni tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” Ọba Israẹli dá Jehoṣafati lóhùn pé, “Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ìbá tún béèrè lọ́wọ́ OLúWA, ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorí kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Mikaiah ọmọ Imla.” “Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀,” Jehoṣafati sì dá lóhùn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, “Ẹ mú Mikaiah ọmọ Imla kí ó yára wá.” Wọ́n wọ aṣọ Ìgúnwà wọn, ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu-bodè Samaria, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. Nísinsin yìí Sedekiah ọmọ Kenaana sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA sọ: pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Siria títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.” Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò kan náà, “Wọ́n sì wí pé, dojúkọ Ramoti Gileadi ìwọ yóò sì ṣẹ́gun,” wọ́n wí pé, “nítorí OLúWA yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” Ìránṣẹ́ tí ó ti lọ pe Mikaiah sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó dàbí ọ̀kan nínú tiwọn, kí o sì sọ rere.” Ṣùgbọ́n Mikaiah wí pe, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé OLúWA ń bẹ láààyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ.” Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Mikaiah, ṣe kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Ramoti Gileadi, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn?” “Ẹ dojúkọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun.” Ó dáhùn, “nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ OLúWA?” Mikaiah sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Israẹli túká kiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, OLúWA sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ” Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?” Mikaiah tẹ̀síwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA: Mo rí OLúWA jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì. OLúWA sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu ọba Israẹli lọ sí Ramoti Gileadi kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’ “Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún. Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá síwájú, ó dúró níwájú OLúWA ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’ “ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ OLúWA béèrè. “ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’ “ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni OLúWA wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ “Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí OLúWA ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. OLúWA sì ti sọ ibi sí ọ.” Nígbà náà Sedekiah ọmọ Kenaana lọ sókè ó sì gbá Mikaiah ní ojú. Ó sì béèrè pé, “Ní ọ̀nà wo ni ẹ̀mí OLúWA gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?” Mikaiah sì dáhùn pé, “ìwọ yóò ṣe ìwádìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sápamọ́ sínú ìyẹ̀wù.” Ọba Israẹli pa á láṣẹ pé, “Mú Mikaiah kí o sì ran padà sí Amoni olórí ìlú àti sí Joaṣi ọmọ ọba, Ó sì wí pé ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ: ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ” Mikaiah sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, OLúWA kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún un pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda lọ sókè ní Ramoti Gileadi. Ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà. Nísinsin yìí ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Israẹli.” Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jehoṣafati, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati kégbe sókè, OLúWA sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ rí i wí pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró. Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.” Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ sí i, ọba Israẹli dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Siria títí ó fi di àṣálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú.