I. Tim 6:1-2
I. Tim 6:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
KI gbogbo awọn ti iṣe ẹrú labẹ ìrú mã ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọla gbogbo, ki a má bã sọrọ-odi si orukọ Ọlọrun ati ẹkọ́ rẹ̀. Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ́, ki nwọn máṣe gàn wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mã sìn wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ́ ati olufẹ. Nkan wọnyi ni ki o mã kọ́ni ki o si mã fi gba-ni-niyanju.
I. Tim 6:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àjàgà ẹrú níláti rí i pé wọ́n ń bu ọlá fún àwọn ọ̀gá wọn ní ọ̀nà gbogbo, kí àwọn eniyan má baà sọ̀rọ̀ ìṣáátá sí orúkọ Ọlọrun ati ẹ̀kọ́ onigbagbọ. Àwọn ẹrú tí wọ́n ní ọ̀gá onigbagbọ kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di ẹgbẹ́ ọ̀gá wọn, wọn ìbáà jẹ́ ará ninu Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti sìn wọ́n tara-tara, nítorí àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún jẹ́ arakunrin ninu igbagbọ ati ìfẹ́. Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa fi kọ́ àwọn eniyan, kí o sì máa fi gbà wọ́n níyànjú.
I. Tim 6:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú.