I. Tim 4:11-16
I. Tim 4:11-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni. Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́. Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni. Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba. Mã fiyesi nkan wọnyi; fi ara rẹ fun wọn patapata; ki ilọsiwaju rẹ ki o le hàn gbangba fun gbogbo enia. Mã ṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ́ rẹ; mã duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ rẹ là.
I. Tim 4:11-16 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa pa láṣẹ, kí o sì máa kọ́ àwọn eniyan. Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kẹ́gàn rẹ, nítorí pé o jẹ́ ọ̀dọ́. Ṣugbọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn onigbagbọ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, ati ninu ìṣe rẹ, ninu ìfẹ́, ninu igbagbọ ati ninu ìwà pípé. Kí n tó dé, tẹra mọ́ kíka ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ati gbígba àwọn eniyan níyànjú, ati iṣẹ́ olùkọ́ni. Má ṣe àìnáání ẹ̀bùn tí Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí àwọn àgbà ìjọ gbé ọwọ́ lé ọ lórí. Máa lépa àwọn nǹkan wọnyi. Àwọn ni kí o jẹ́ kí ó gba gbogbo àkókò rẹ, kí ìtẹ̀síwájú rẹ lè hàn sí gbogbo eniyan. Máa ṣọ́ ara rẹ ati ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró ṣinṣin ninu wọn. Tí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo gba ara rẹ là ati àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.
I. Tim 4:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́, Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbani-níyànjú àti ìkọ́ni. Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà. Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn. Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.