I. Tim 3:1-7
I. Tim 3:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ. Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ. Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo; Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo; (Ṣugbọn bi enia kò ba mọ̀ bi ã ti ṣe ikawọ ile ara rẹ̀, on o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?) Ki o má jẹ ẹni titun, kí o má bã gbéraga, ki o si ṣubu sinu ẹbi Èṣu. O si yẹ kí o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn ti mbẹ lode: kí o má ba bọ sinu ẹ̀gan ati sinu idẹkun Èṣu.
I. Tim 3:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí: bí ẹnikẹ́ni bá dàníyàn láti jẹ́ olùdarí, iṣẹ́ rere ni ó fẹ́ ṣe. Nítorí náà, olùdarí níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn; kò gbọdọ̀ ní ju iyawo kan lọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ọlọ́gbọ́n eniyan, ọmọlúwàbí, ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa ṣe eniyan lálejò, tí ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ni. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, tabi ẹni tí máa ń lu eniyan. Ṣugbọn kí ó jẹ́ onífaradà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ alásọ̀, tabi ẹni tí ó ní ọ̀kánjúwà owó. Ó gbọdọ̀ káwọ́ ilé rẹ̀ dáradára, kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Nítorí ẹni tí kò káwọ́ ilé ara rẹ̀, báwo ni ó ṣe lè mójútó ìjọ Ọlọrun? Kí ó má jẹ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onigbagbọ, kí ó má baà gbéraga, kí ó wá bọ́ sọ́wọ́ Satani. Ṣugbọn kí ó jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe onigbagbọ, kí ó má baà bọ̀ sinu ẹ̀gàn, kí tàkúté Satani má baà mú un.
I. Tim 3:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò alábojútó, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́, Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí oníjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó. Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo; Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó ha ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run? Kí ó má jẹ́ ẹni tuntun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má ba à gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi èṣù. Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má ba à bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ̀kùn èṣù.