I. Tim 2:1-6
I. Tim 2:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA mo gbà nyin niyanju ṣaju ohun gbogbo, pe ki a mã bẹ̀bẹ, ki a mã gbadura, ki a mã ṣìpẹ, ati ki a mã dupẹ nitori gbogbo enia; Fun awọn ọba, ati gbogbo awọn ti o wà ni ipo giga; ki a le mã lo aiye wa ni idakẹjẹ ati pẹlẹ ninu gbogbo ìwa-bi-Ọlọrun ati ìwa agbà. Nitori eyi dara o si ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun Olugbala wa; Ẹniti o nfẹ ki gbogbo enia ni igbala ki nwọn si wá sinu ìmọ otitọ. Nitori Ọlọrun kan ni mbẹ, Onilaja kan pẹlu larin Ọlọrun ati enia, on papa enia, ani Kristi Jesu; Ẹniti o fi ara rẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo enia, ẹrí li akokò rẹ̀
I. Tim 2:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, lákọ̀ọ́kọ́, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o máa tọrọ ninu adura, kí o máa bẹ̀bẹ̀, kí o sì máa dúpẹ́ fún gbogbo eniyan, fún àwọn ọba, ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ipò gíga, pé kí á máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí á máa gbé ìgbé-ayé bí olùfọkànsìn ati bí ọmọlúwàbí. Irú adura báyìí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọrun Olùgbàlà wa, ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo eniyan rí ìgbàlà, tí ó sì fẹ́ kí wọn ní ìmọ̀ òtítọ́. Nítorí Ọlọrun kan ni ó wà, alárinà kan ni ó sì wà láàrin Ọlọrun ati eniyan; olúwarẹ̀ ni Kristi Jesu, tí òun náà jẹ́ eniyan, tí ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo eniyan. Èyí ni ẹ̀rí pé, Ọlọrun ṣe ètò pé kí gbogbo eniyan lè ní ìgbàlà nígbà tí àkókò rẹ̀ tó.
I. Tim 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn. Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́. Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa; Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́. Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà. Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ.