I. Tim 1:2-4
I. Tim 1:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Si Timotiu, ọmọ mi tõtọ ninu igbagbọ́: Ore-ọfẹ, ãnu, alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa. Bi mo ti gba ọ niyanju lati joko ni Efesu, nigbati mo nlọ si Makedonia, ki iwọ ki o le paṣẹ fun awọn kan, ki nwọn ki o máṣe kọ́ni li ẹkọ́ miran, Ki nwọn má si ṣe fiyesi awọn itan lasan, ati ti ìran ti kò li opin, eyiti imã mú ijiyan wa dipo iṣẹ iriju Ọlọrun ti mbẹ ninu igbagbọ́; bẹni mo ṣe nisisiyi.
I. Tim 1:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Sí Timoti ọmọ mi tòótọ́ ninu igbagbọ. Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Oluwa wa, kí ó máa wà pẹlu rẹ. Nígbà tí mò ń lọ sí Masedonia, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o dúró ní Efesu, kí o pàṣẹ fún àwọn kan kí wọn má ṣe kọ́ eniyan ní ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà, kí wọn má jókòó ti àwọn ìtàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ati ìtàn ìrandíran tí kò lópin, tí ó máa ń mú àríyànjiyàn wá, dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọrun tí a mọ̀ nípa igbagbọ.
I. Tim 1:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sí Timotiu ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jesu Kristi Olúwa wa. Bí mo ṣe rọ̀ yìn nígbà tí mò ń lọ sí Makedonia, ẹ dúró ní Efesu, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́ kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn asán, àti ìtàn ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́.