I. Tes 5:1-3
I. Tes 5:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN niti akokò ati ìgba wọnni, ará, ẹnyin kò tun fẹ ki a kọ ohunkohun si nyin, Nitoripe ẹnyin tikaranyin mọ̀ dajudaju pe, ọjọ Oluwa mbọ̀wá gẹgẹ bi olè li oru. Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojijì yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyun; nwọn kì yio si le sálà.
I. Tes 5:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín mọ́ nípa ti àkókò ati ìgbà tí Oluwa yóo farahàn. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀ dájú pé bí ìgbà tí olè bá dé lóru ni ọjọ́ tí Oluwa yóo dé yóo rí. Nígbà tí àwọn eniyan bá ń wí pé, “Àkókò alaafia ati ìrọ̀ra nìyí,” nígbà náà ni ìparun yóo dé bá wọn lójijì, wọn kò sì ní ríbi sá sí; yóo dàbí ìgbà tí obinrin bá lóyún, tí kò mọ ìgbà tí òun yóo bí.
I. Tes 5:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, ará, a kò nílò láti kọ ìwé sí i yín mọ́ nípa àkókò àti ìgbà, nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru. Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí.