I. Tes 4:3-8
I. Tes 4:3-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ́ nyin, pe ki ẹnyin ki o takéte si àgbere: Ki olukuluku nyin le mọ̀ bi on iba ti mã ko ohun èlo rẹ̀ ni ijanu ni ìwa-mimọ́ ati ni ọlá; Kì iṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti kò mọ̀ Ọlọrun: Ki ẹnikẹni máṣe rekọja, ki o má si ṣe ṣẹ arakunrin rẹ̀ ninu nkan na: nitori Oluwa ni olugbẹsan ninu gbogbo nkan wọnyi, gẹgẹ bi awa ti kilọ fun nyin tẹlẹ, ti a si jẹri pẹlu. Nitori Ọlọrun kò pè wa fun ìwa ẽri, ṣugbọn ni ìwamimọ́. Nitorina ẹnikẹni ti o bá kọ̀, ko kọ̀ enia, bikoṣe Ọlọrun, ẹniti o fun nyin ni Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ pẹlu.
I. Tes 4:3-8 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ìfẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ ya ara yín sí mímọ́: ẹ jìnnà sí àgbèrè. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mọ ọ̀nà láti máa bá aya rẹ̀ gbé pọ̀ pẹlu ìwà mímọ́ ati iyì, kì í ṣe pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara bíi ti àwọn abọ̀rìṣà tí kò mọ Ọlọrun. Èyí kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ̀, tabi kí ó ṣẹ arakunrin rẹ̀ nípa ọ̀ràn yìí. Nítorí ẹlẹ́san ni Oluwa ninu àwọn ọ̀ràn wọnyi, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, tí a wá tún ń kìlọ̀ fun yín nisinsinyii. Nítorí Ọlọrun kò pè wá sí ìwà èérí bíkòṣe ìwà mímọ́. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kọ ọ̀rọ̀ yìí, kì í ṣe ọ̀rọ̀ eniyan ni ó kọ̀ bíkòṣe Ọlọrun tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fun yín.
I. Tes 4:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ jẹ́ mímọ́, kí ẹ sì yàgò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kọ́ láti ṣàkóso ara rẹ̀ ní ọ̀nà mímọ́ àti pẹ̀lú ọlá, kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run; àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni nínú yín máa ṣe rẹ arákùnrin rẹ̀ jẹ nípa ohunkóhun. Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú ìwà èérí, bí kò ṣe sínú ìgbé ayé mímọ́. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í ṣe òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.