I. Tes 3:1-3
I. Tes 3:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA nigbati ara wa kò gba a mọ́, awa rò pe o dara ki a fi awa nikan sẹhin ni Ateni; Awa si rán Timotiu, arakunrin wa, ati iranṣẹ Ọlọrun ninu ihinrere Kristi, lati fi ẹsẹ nyin mulẹ, ati lati tù nyin ninu niti igbagbọ́ nyin: Ki a máṣe mu ẹnikẹni yẹsẹ nipa wahalà wọnyi: nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ pe a ti yàn wa sinu rẹ̀.
I. Tes 3:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, nígbà tí ara wa kò gbà á mọ́, a pinnu pé kí ó kúkú ku àwa nìkan ní Atẹni; ni a bá rán Timoti si yín, ẹni tí ó jẹ́ arakunrin wa ati alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun ninu iṣẹ́ ìyìn rere ti Kristi, kí ó lè máa gbà yín níyànjú, kí igbagbọ yín lè dúró gbọnin-gbọnin. Kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ ní àkókò inúnibíni yìí. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé onigbagbọ níláti rí irú ìrírí yìí.
I. Tes 3:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Ateni. Awa sì rán Timotiu, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Ọlọ́run nínú ìhìnrere Kristi, láti fi ẹsẹ yín múlẹ̀, àti láti tù yín nínú ní ti ìgbàgbọ́ yín. Láìsí àní àní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwọn tí ó gbàgbọ́, kí a má ba dààmú.