I. Tes 2:8-9
I. Tes 2:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ gẹgẹ bi awa ti ni ifẹ inu rere si nyin, inu wa dun jọjọ lati fun nyin kì iṣe ihinrere Ọlọrun nikan, ṣugbọn ẹmí awa tikarawa pẹlu, nitoriti ẹnyin jẹ ẹni ọ̀wọ́n fun wa. Nitori ẹnyin ranti, ará, ìṣẹ́ ati lãlã wa: nitori awa nṣe lãlã li ọsán ati li oru, ki awa ko má bã di ẹrù ru ẹnikẹni ninu nyin, awa wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin.
I. Tes 2:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wa fà sọ́dọ̀ yín; kì í ṣe ìyìn rere nìkan ni a fẹ́ fun yín, ṣugbọn ó dàbí ẹni pé kí á gbé gbogbo ara wa fun yín, nítorí ẹ ṣọ̀wọ́n fún wa. Ará, ẹ ranti ìṣòro ati làálàá wa, pé tọ̀sán-tòru ni à ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wa, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára nígbà tí à ń waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín.
I. Tes 2:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa. Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín.