I. Tes 2:3-6 - Compare All Versions

I. Tes 2:3-6 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nitori ọ̀rọ iyanju wa kì iṣe ti ẹ̀tan, tabi ti ìwa aimọ́, tabi ninu arekereke: Ṣugbọn bi a ti kà wa yẹ lati ọdọ Ọlọrun wá bi ẹniti a fi ihinrere le lọwọ, bẹ̃ li awa nsọ; kì iṣe bi ẹniti nwù enia bikoṣe Ọlọrun, ti ndan ọkàn wa wò. Nitori awa kò lo ọrọ ipọnni nigbakan rí gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, tabi iboju ojukòkoro; Ọlọrun li ẹlẹri: Bẹni awa kò wá ogo lọdọ enia, tabi lọdọ nyin, tabi lọdọ awọn ẹlomiran, nigbati awa iba fẹ ọla lori nyin bi awọn aposteli Kristi.

I. Tes 2:3-6 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè. Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò. A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa. A kò béèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi a ò bá ti di àjàgà fún un yín.

I. Tes 2:3-6 YCE (Yoruba Bible)

Nítorí pé ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ohun ìṣìnà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun èérí tabi ti ìtànjẹ. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti kà wá yẹ, tí ó fi iṣẹ́ ìyìn rere lé wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe láti tẹ́ eniyan lọ́rùn, bíkòṣe pé láti tẹ́ Ọlọrun tí ó mọ ọkàn wa lọ́rùn. Nítorí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, a kò wá pọ́n ẹnikẹ́ni, a kò sì wá ṣe àṣehàn bí ẹni tí ìwọ̀ra wà lọ́kàn rẹ̀. A fi Ọlọrun ṣe ẹlẹ́rìí! Bẹ́ẹ̀ ni a kò wá ìyìn eniyan, ìbáà ṣe láti ọ̀dọ̀ yín, tabi láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn