I. Tes 2:13-16
I. Tes 2:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori eyi li awa ṣe ndupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu li aisimi, pe nigbati ẹnyin gba ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ lọdọ wa, ani ọ̀rọ Ọlọrun, ẹnyin kò gbà a bi ẹnipe ọ̀rọ enia, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti jẹ nitõtọ, bi ọ̀rọ Ọlọrun, eyiti o ṣiṣẹ gidigidi ninu ẹnyin ti o gbagbọ́ pẹlu. Nitori, ará, ẹnyin di alafarawe awọn ijọ Ọlọrun ti mbẹ ni Judea, ninu Kristi Jesu: nitoripe ẹnyin pẹlu jìya iru ohun kanna lọwọ awọn ara ilu nyin, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti jìya lọwọ awọn Ju: Awọn ẹniti o pa Jesu Oluwa, ati awọn woli, nwọn si tì wa jade; nwọn kò si ṣe eyiti o wu Ọlọrun, nwọn si wà lodi si gbogbo enia: Nwọn kọ̀ fun wa lati sọ̀rọ fun awọn Keferi ki nwọn ki o le là, lati mã sọ ẹ̀ṣẹ wọn di kikun nigbagbogbo: ṣugbọn ibinu de bá wọn titi de opin.
I. Tes 2:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Nítorí, ẹ ti di aláfarawé àwọn ìjọ Ọlọrun tí ó wà ninu Kristi Jesu ní ilẹ̀ Judia, nítorí irú ìyà tí wọ́n jẹ lọ́wọ́ àwọn Juu ni ẹ̀yin náà jẹ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà tiyín. Àwọn Juu yìí ni wọ́n pa Oluwa Jesu ati àwọn wolii, tí wọ́n sì fi inúnibíni lé wa jáde. Wọn kò ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, wọ́n sì ń lòdì sí àwọn ohun tí ó lè ṣe eniyan ní anfaani. Wọ́n ń ṣe ìdínà fún wa kí á má baà lè waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu, kí wọn má baà rí ìgbàlà, kí òṣùnwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ wọn baà lè kún. Ṣugbọn ibinu Ọlọrun ti dé sórí wọn.
I. Tes 2:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́ṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tí o wà ní Judea nínú Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ̀yin pẹ̀lú jìyà irú ohun kan náà lọ́wọ́ àwọn ará ìlú yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù, àwọn tí wọ́n pa Jesu Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìhìnrere dúró láàrín àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń di púpọ̀ sí i lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.