I. Tes 2:1-6
I. Tes 2:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORI ẹnyin tikaranyin mọ̀, ará, irú iwọle wa si nyin pe kì iṣe lasan: Ṣugbọn lẹhin ti awa ti jìya ṣaju, ti a si ti lo wa ni ilo itiju ni Filippi gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, awa ni igboiya ninu Ọlọrun wa lati sọ̀rọ ihinrere Ọlọrun fun nyin pẹlu ọ̀pọlọpọ ìwàyá ìjà. Nitori ọ̀rọ iyanju wa kì iṣe ti ẹ̀tan, tabi ti ìwa aimọ́, tabi ninu arekereke: Ṣugbọn bi a ti kà wa yẹ lati ọdọ Ọlọrun wá bi ẹniti a fi ihinrere le lọwọ, bẹ̃ li awa nsọ; kì iṣe bi ẹniti nwù enia bikoṣe Ọlọrun, ti ndan ọkàn wa wò. Nitori awa kò lo ọrọ ipọnni nigbakan rí gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, tabi iboju ojukòkoro; Ọlọrun li ẹlẹri: Bẹni awa kò wá ogo lọdọ enia, tabi lọdọ nyin, tabi lọdọ awọn ẹlomiran, nigbati awa iba fẹ ọla lori nyin bi awọn aposteli Kristi.
I. Tes 2:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ará, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé wíwá tí a wá sọ́dọ̀ yín kì í ṣe lásán. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, lẹ́yìn tí a ti jìyà, tí a ti rí ẹ̀gbin ní Filipi, ni a fi ìgboyà nípa Ọlọrun wá tí a sọ̀rọ̀ ìyìn rere Ọlọrun fun yín láàrin ọpọlọpọ àtakò. Nítorí pé ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ohun ìṣìnà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun èérí tabi ti ìtànjẹ. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti kà wá yẹ, tí ó fi iṣẹ́ ìyìn rere lé wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe láti tẹ́ eniyan lọ́rùn, bíkòṣe pé láti tẹ́ Ọlọrun tí ó mọ ọkàn wa lọ́rùn. Nítorí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, a kò wá pọ́n ẹnikẹ́ni, a kò sì wá ṣe àṣehàn bí ẹni tí ìwọ̀ra wà lọ́kàn rẹ̀. A fi Ọlọrun ṣe ẹlẹ́rìí! Bẹ́ẹ̀ ni a kò wá ìyìn eniyan, ìbáà ṣe láti ọ̀dọ̀ yín, tabi láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn
I. Tes 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin pàápàá mọ̀ ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán. Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìhìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle. Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè. Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìhìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò. A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa. A kò béèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi a ò bá ti di àjàgà fún un yín.