I. Tes 2:1-3
I. Tes 2:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORI ẹnyin tikaranyin mọ̀, ará, irú iwọle wa si nyin pe kì iṣe lasan: Ṣugbọn lẹhin ti awa ti jìya ṣaju, ti a si ti lo wa ni ilo itiju ni Filippi gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, awa ni igboiya ninu Ọlọrun wa lati sọ̀rọ ihinrere Ọlọrun fun nyin pẹlu ọ̀pọlọpọ ìwàyá ìjà. Nitori ọ̀rọ iyanju wa kì iṣe ti ẹ̀tan, tabi ti ìwa aimọ́, tabi ninu arekereke
I. Tes 2:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ará, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé wíwá tí a wá sọ́dọ̀ yín kì í ṣe lásán. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, lẹ́yìn tí a ti jìyà, tí a ti rí ẹ̀gbin ní Filipi, ni a fi ìgboyà nípa Ọlọrun wá tí a sọ̀rọ̀ ìyìn rere Ọlọrun fun yín láàrin ọpọlọpọ àtakò. Nítorí pé ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ohun ìṣìnà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun èérí tabi ti ìtànjẹ.
I. Tes 2:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin pàápàá mọ̀ ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán. Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìhìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle. Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè.