I. Tes 1:9-10
I. Tes 1:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe awọn tikarawọn ròhin nipa wa, irú iwọle ti awa ti ni sọdọ nyin, bi ẹnyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ère lati mã sìn Ọlọrun alãye ati otitọ; Ati lati duro dè Ọmọ rẹ̀ lati ọrun wá, ẹniti o si ji dide kuro ninu okú, ani Jesu na, ẹniti ngbà wa kuro ninu ibinu ti mbọ̀.
I. Tes 1:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí wọ́n ń sọ bí ẹ ti ṣe gbà wá nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, ati bí ẹ ti ṣe yipada kúrò ninu ìbọ̀rìṣà, láti máa sin Ọlọrun tòótọ́ tíí ṣe Ọlọrun alààyè; ati bí ẹ ti ń retí Jesu, Ọmọ rẹ̀, láti ọ̀run wá, ẹni tí a jí dìde ninu òkú, tí ó yọ wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀.
I. Tes 1:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò. Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè àti òtítọ́ nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn, àti láti fi ojú ṣọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.