I. Tes 1:6-8
I. Tes 1:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin si di alafarawe wa, ati ti Oluwa, lẹhin ti ẹnyin ti gbà ọ̀rọ na ninu ipọnju ọ̀pọlọpọ, pẹlu ayọ̀ Ẹmí Mimọ́: Ti ẹnyin si jẹ apẹrẹ fun gbogbo awọn ti o gbagbọ́ ni Makedonia ati Akaia. Nitori lati ọdọ nyin lọ li ọ̀rọ Oluwa ti dún jade, kì iṣe ni kìki Makedonia ati Akaia nikan, ṣugbọn ni ibi gbogbo ni ìhin igbagbọ́ nyin si Ọlọrun tàn kalẹ; tobẹ̃ ti awa kò ni isọ̀rọ ohunkohun.
I. Tes 1:6-8 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin náà wá ń fara wé wa, ẹ sì ń fara wé Oluwa. Láàrin ọpọlọpọ inúnibíni ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere tayọ̀tayọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ wá di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà ní Masedonia ati Akaya. Nítorí ẹ̀yin ni ẹ tan ìyìn rere ọ̀rọ̀ Oluwa káàkiri, kì í ṣe ní Masedonia ati Akaya nìkan, ṣugbọn níbi gbogbo ni ìròyìn igbagbọ yín sí Ọlọrun ti tàn dé. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní pé à ń sọ ohunkohun mọ́.
I. Tes 1:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín. Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní agbègbè Makedonia àti Akaia. Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbègbè Makedonia àti Akaia lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀.