I. Tes 1:1-3
I. Tes 1:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ awọn ara Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba, ati ninu Jesu Kristi Oluwa: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa. Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo fun gbogbo nyin, awa nṣe iranti nyin ninu adura wa; Li aisimi li awa nranti iṣẹ igbagbọ́ nyin ati lãla ifẹ ati sũru ireti nyin ninu Oluwa wa Jesu Kristi, niwaju Ọlọrun ati Baba wa
I. Tes 1:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia máa wà pẹlu yín. À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí gbogbo yín, a sì ń ranti yín ninu adura wa nígbà gbogbo. Ninu adura wa sí Ọlọrun Baba wa, à ń ranti bí igbagbọ yín ti ń mú kí ẹ ṣiṣẹ́, tí ìfẹ́ yín ń jẹ́ kí ẹ ṣe akitiyan, tí ìrètí tí ẹ ní ninu Oluwa wa Jesu Kristi sì ń mú kí ẹ ní ìfaradà.
I. Tes 1:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu, Sila àti Timotiu. A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi. Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín. Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú. A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa.