I. Tes 1:1-10
I. Tes 1:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ awọn ara Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba, ati ninu Jesu Kristi Oluwa: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa. Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo fun gbogbo nyin, awa nṣe iranti nyin ninu adura wa; Li aisimi li awa nranti iṣẹ igbagbọ́ nyin ati lãla ifẹ ati sũru ireti nyin ninu Oluwa wa Jesu Kristi, niwaju Ọlọrun ati Baba wa; Nitoripe awa mọ yiyan nyin, ara olufẹ ti Ọlọrun, Bi ihinrere wa kò ti wá sọdọ nyin li ọ̀rọ nikan, ṣugbọn li agbara pẹlu, ati ninu Ẹmí Mimọ́, ati ni ọ̀pọlọpọ igbẹkẹle; bi ẹnyin ti mọ̀ irú enia ti awa jẹ́ larin nyin nitori nyin. Ẹnyin si di alafarawe wa, ati ti Oluwa, lẹhin ti ẹnyin ti gbà ọ̀rọ na ninu ipọnju ọ̀pọlọpọ, pẹlu ayọ̀ Ẹmí Mimọ́: Ti ẹnyin si jẹ apẹrẹ fun gbogbo awọn ti o gbagbọ́ ni Makedonia ati Akaia. Nitori lati ọdọ nyin lọ li ọ̀rọ Oluwa ti dún jade, kì iṣe ni kìki Makedonia ati Akaia nikan, ṣugbọn ni ibi gbogbo ni ìhin igbagbọ́ nyin si Ọlọrun tàn kalẹ; tobẹ̃ ti awa kò ni isọ̀rọ ohunkohun. Nitoripe awọn tikarawọn ròhin nipa wa, irú iwọle ti awa ti ni sọdọ nyin, bi ẹnyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ère lati mã sìn Ọlọrun alãye ati otitọ; Ati lati duro dè Ọmọ rẹ̀ lati ọrun wá, ẹniti o si ji dide kuro ninu okú, ani Jesu na, ẹniti ngbà wa kuro ninu ibinu ti mbọ̀.
I. Tes 1:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia máa wà pẹlu yín. À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí gbogbo yín, a sì ń ranti yín ninu adura wa nígbà gbogbo. Ninu adura wa sí Ọlọrun Baba wa, à ń ranti bí igbagbọ yín ti ń mú kí ẹ ṣiṣẹ́, tí ìfẹ́ yín ń jẹ́ kí ẹ ṣe akitiyan, tí ìrètí tí ẹ ní ninu Oluwa wa Jesu Kristi sì ń mú kí ẹ ní ìfaradà. Ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Ọlọrun, a mọ̀ pé Ọlọrun ni ó yàn yín. Nígbà tí a mú ìyìn rere wá sí ọ̀dọ̀ yín, a kò mú un wá pẹlu ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan; ṣugbọn pẹlu agbára ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni, ati pẹlu ọpọlọpọ ẹ̀rí tí ó dáni lójú. Ẹ̀yin náà kúkú ti mọ irú ẹni tí a jẹ́ nítorí tiyín nígbà tí a wà láàrin yín. Ẹ̀yin náà wá ń fara wé wa, ẹ sì ń fara wé Oluwa. Láàrin ọpọlọpọ inúnibíni ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere tayọ̀tayọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ wá di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà ní Masedonia ati Akaya. Nítorí ẹ̀yin ni ẹ tan ìyìn rere ọ̀rọ̀ Oluwa káàkiri, kì í ṣe ní Masedonia ati Akaya nìkan, ṣugbọn níbi gbogbo ni ìròyìn igbagbọ yín sí Ọlọrun ti tàn dé. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní pé à ń sọ ohunkohun mọ́. Nítorí wọ́n ń sọ bí ẹ ti ṣe gbà wá nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, ati bí ẹ ti ṣe yipada kúrò ninu ìbọ̀rìṣà, láti máa sin Ọlọrun tòótọ́ tíí ṣe Ọlọrun alààyè; ati bí ẹ ti ń retí Jesu, Ọmọ rẹ̀, láti ọ̀run wá, ẹni tí a jí dìde ninu òkú, tí ó yọ wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀.
I. Tes 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu, Sila àti Timotiu. A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi. Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín. Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú. A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa. Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí a mú ìhìnrere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrín yín nítorí yín. Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín. Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní agbègbè Makedonia àti Akaia. Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbègbè Makedonia àti Akaia lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀. Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò. Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè àti òtítọ́ nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn, àti láti fi ojú ṣọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.