I. Sam 9:1-2
I. Sam 9:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ ọkunrin kan ara Benjamini si wà, a ma pe orukọ rẹ̀ ni Kiṣi, ọmọ Abeli, ọmọ Sesori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afia, ara Benjamini ọkunrin alagbara. On si ni ọmọkunrin kan, ẹniti a npè ni Saulu, ọdọmọkunrin ti o yàn ti o si ṣe arẹwa, kò si si ẹniti o dara ju u lọ ninu gbogbo awọn ọmọ Israeli: lati ejika rẹ̀ lọ si oke, o ga jù gbogbo awọn enia na lọ.
I. Sam 9:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afaya láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó ní ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Saulu. Saulu yìí jẹ́ arẹwà ọkunrin. Láti èjìká rẹ̀ sókè ni ó fi ga ju ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ, ó sì lẹ́wà ju ẹnikẹ́ni ninu wọn lọ.
I. Sam 9:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ará Benjamini kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afiah ti Benjamini. Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Saulu, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàrín gbogbo àwọn ọmọ Israẹli—láti èjìká rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn tókù lọ.