I. Sam 8:7-9 - Compare All Versions

I. Sam 8:7-9 YBCV (Bibeli Mimọ)

Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn awọn enia na ni gbogbo eyi ti nwọn sọ fun ọ: nitoripe iwọ ki nwọn kọ̀, ṣugbọn emi ni nwọn kọ̀ lati jẹ ọba lori wọn. Gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti nwọn ṣe lati ọjọ ti mo ti mu nwọn jade ti Egipti wá, titi o si fi di oni, bi nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn si nsin awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni nwọn ṣe si ọ pẹlu. Njẹ nitorina gbọ́ ohùn wọn: ṣugbọn lẹhin igbati iwọ ba ti jẹri si wọn tan, nigbana ni ki iwọ ki o si fi iwà ọba ti yio jẹ lori wọn hàn wọn.

I. Sam 8:7-9 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

OLúWA sì sọ fún Samuẹli pé, “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Ejibiti títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ. Nísinsin yìí, gbọ́ tiwọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáradára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”

I. Sam 8:7-9 YCE (Yoruba Bible)

OLUWA dá Samuẹli lóhùn, ó ní, “Gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn eniyan náà wí fún ọ, nítorí pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ lọ́ba. Láti ìgbà tí mo ti kó wọn wá láti Ijipti títí di òní ni wọ́n ti kọ̀yìn sí mi, tí wọ́n sì ń bọ oriṣa. Ohun tí wọ́n ti ń ṣe sí mi ni wọ́n ń ṣe sí ọ yìí. Nítorí náà, gbọ́ tiwọn, ṣugbọn kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí o sì ṣe àlàyé gbogbo ohun tí ọba náà yóo máa ṣe sí wọn fún wọn dáradára.”