I. Sam 8:4-5
I. Sam 8:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo awọn agbà Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn si tọ Samueli lọ si Rama, Nwọn si wi fun u pe, Kiye si i, iwọ di arugbo, awọn ọmọ rẹ kò si rin ni ìwa rẹ: njẹ fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki o le ma ṣe idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ède.
Pín
Kà I. Sam 8I. Sam 8:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama; wọ́n wí fún un pé, “Wò ó, àgbà ti dé sí ọ, àwọn ọmọ rẹ kò sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere rẹ. Yan ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọba fún wa, tí yóo máa ṣe alákòóso wa bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.”
Pín
Kà I. Sam 8I. Sam 8:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama. Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsin yìí, yan ọba fún wa kí ó lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀-èdè.”
Pín
Kà I. Sam 8