I. Sam 7:2-17
I. Sam 7:2-17 Yoruba Bible (YCE)
Láti ìgbà náà, Kiriati Jearimu ni wọ́n gbé àpótí OLUWA sí fún nǹkan bíi ogún ọdún, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ń ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹ bá fẹ́ pada sọ́dọ̀ OLUWA tọkàntọkàn, ẹ gbọdọ̀ kó gbogbo oriṣa ati gbogbo ère oriṣa Aṣitarotu, tí ó wà lọ́dọ̀ yín dànù; ẹ palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún OLUWA, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo; yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” Àwọn ọmọ Israẹli bá kó gbogbo oriṣa Baali ati ti Aṣitarotu wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA nìkan. Samuẹli ní kí wọ́n kó gbogbo eniyan Israẹli jọ sí Misipa, ó ní òun óo gbadura sí OLUWA fún wọn níbẹ̀. Gbogbo wọn bá péjọ sí Misipa, wọ́n pọn omi, wọ́n dà á sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ètùtù níwájú OLUWA. Wọ́n gbààwẹ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Samuẹli sì ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan Israẹli ní Misipa. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli péjọ sí Misipa, àwọn ọba Filistini kó àwọn eniyan wọn jọ láti gbógun tì wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n. Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Má dákẹ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” Samuẹli pa ọmọ aguntan kan tí ó ṣì ń mu ọmú, ó sun ún lódidi, ó fi rúbọ sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó gbadura sí OLUWA fún ìrànlọ́wọ́ Israẹli; OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀. Nígbà tí Samuẹli ń rúbọ lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, láti bá wọn jagun. Ṣugbọn OLUWA sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run wá. Ìdààmú bá wọn, wọ́n sì túká pẹlu ìpayà. Àwọn ọmọ Israẹli bá kó ogun jáde láti Misipa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ ogun Filistini lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìsàlẹ̀ Betikari, wọ́n ń pa wọ́n bí wọ́n ti ń lé wọn lọ. Samuẹli gbé òkúta kan, ó rì í mọ́lẹ̀ láàrin Misipa ati Ṣeni, ó sì sọ ibẹ̀ ni Ebeneseri, ó ní, “OLUWA ràn wá lọ́wọ́ títí dé ìhín yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹgun àwọn ará Filistia, wọn kò sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli mọ́. OLUWA n ṣe àwọn ará Filistia níbi ní gbogbo ọjọ́ ayé Samuẹli. Gbogbo ìlú tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, láti Ekironi títí dé Gati, ni wọ́n dá pada fún wọn. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ilẹ̀ wọn pada lọ́wọ́ àwọn ará Filistia. Alaafia wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará Amori. Samuẹli jẹ́ adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí tí ó fi kú. Lọdọọdun níí máa ń lọ yípo Bẹtẹli, Giligali, ati Misipa, láti ṣe ìdájọ́. Lẹ́yìn náà, yóo pada lọ sí ilé rẹ̀, ní Rama, nítorí pé a máa dájọ́ fún àwọn eniyan níbẹ̀ pẹlu. Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA.
I. Sam 7:2-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, lati igba ti apoti Oluwa fi wà ni Kirjatjearimu, ọjọ na pẹ́; o si jẹ ogun ọdun: gbogbo ile Israeli si pohunrere ẹkun si Oluwa. Samueli si sọ fun gbogbo ile Israeli, wipe, Bi ẹnyin ba fi gbogbo ọkàn nyin yipada si Oluwa, ẹ mu ajeji ọlọrun wọnni, ati Aṣtaroti kuro larin nyin, ki ẹnyin ki o si pese ọkàn nyin silẹ fun Oluwa, ki ẹ si ma sin on nikanṣoṣo: yio si gbà nyin lọwọ́ Filistini. Awọn ọmọ Israeli si mu Baalimu ati Aṣtaroti kuro, nwọn si sìn Oluwa nikan. Samueli si wipe, Pe gbogbo Israeli jọ si Mispe, emi o si bẹbẹ si Oluwa fun nyin, Nwọn si pejọ si Mispe, nwọn pọn omi, nwọn si tú u silẹ niwaju Oluwa, nwọn gbawẹ li ọjọ na, nwọn si wi nibẹ pe, Awa ti dẹṣẹ si Oluwa. Samueli si ṣe idajọ awọn ọmọ Israeli ni Mispe. Awọn Filistini si gbọ́ pe, awọn ọmọ Israeli pejọ si Mispe, awọn ijoye Filistini si goke tọ Israeli lọ. Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, nwọn bẹ̀ru awọn Filistini. Awọn ọmọ Israeli si wi fun Samueli pe, Máṣe dakẹ ati ma ke pe Oluwa Ọlọrun wa fun wa, yio si gbà wa lọwọ́ awọn Filistini. Samueli mu ọdọ-agutan kan ti nmu ọmu, o si fi i ru ọtọtọ ẹbọ sisun si Oluwa: Samueli si ke pe Oluwa fun Israeli; Oluwa si gbọ́ ọ. Bi Samueli ti nru ẹbọ sisun na lọwọ́, awọn Filistini si sunmọ Israeli lati ba wọn jà: ṣugbọn Oluwa sán ãrá nla li ọjọ na sori awọn Filistini, o si damu wọn, o si pa wọn niwaju Israeli. Awọn ọkunrin Israeli si jade kuro ni Mispe, nwọn si le awọn Filistini, nwọn si npa wọn titi nwọn fi de abẹ Betkari. Samueli si mu okuta kan, o si gbe e kalẹ lagbedemeji Mispe ati Seni, o si pe orukọ rẹ̀ ni Ebeneseri, wipe: Titi de ihin li Oluwa ràn wa lọwọ́. Bẹ̃li a tẹ ori awọn Filistini ba, nwọn kò si tun wá si agbegbe Israeli mọ: ọwọ́ Oluwa si wà ni ibi si awọn Filistini, ni gbogbo ọjọ Samueli. Ilu wọnni eyi ti awọn Filistini ti gbà lọwọ Israeli ni nwọn si fi fun Israeli, lati Ekroni wá titi o fi de Gati; ati agbegbe rẹ̀, ni Israeli gbà silẹ lọwọ́ awọn Filistini. Irẹpọ si wà larin Israeli ati awọn Amori. Samueli ṣe idajọ Israeli ni gbogbo ọjọ rẹ̀. Lati ọdun de ọdun li on ima lọ yika Beteli, ati Gilgali, ati Mispe, on si ṣe idajọ Israeli ni gbogbo ibẹ wọnni. On a si ma yipada si Rama: nibẹ ni ile rẹ̀ gbe wà; nibẹ na li on si ṣe idajọ Israeli, o si tẹ pẹpẹ nibẹ fun Oluwa.
I. Sam 7:2-17 Yoruba Bible (YCE)
Láti ìgbà náà, Kiriati Jearimu ni wọ́n gbé àpótí OLUWA sí fún nǹkan bíi ogún ọdún, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ń ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹ bá fẹ́ pada sọ́dọ̀ OLUWA tọkàntọkàn, ẹ gbọdọ̀ kó gbogbo oriṣa ati gbogbo ère oriṣa Aṣitarotu, tí ó wà lọ́dọ̀ yín dànù; ẹ palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún OLUWA, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo; yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” Àwọn ọmọ Israẹli bá kó gbogbo oriṣa Baali ati ti Aṣitarotu wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA nìkan. Samuẹli ní kí wọ́n kó gbogbo eniyan Israẹli jọ sí Misipa, ó ní òun óo gbadura sí OLUWA fún wọn níbẹ̀. Gbogbo wọn bá péjọ sí Misipa, wọ́n pọn omi, wọ́n dà á sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ètùtù níwájú OLUWA. Wọ́n gbààwẹ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Samuẹli sì ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan Israẹli ní Misipa. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli péjọ sí Misipa, àwọn ọba Filistini kó àwọn eniyan wọn jọ láti gbógun tì wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n. Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Má dákẹ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” Samuẹli pa ọmọ aguntan kan tí ó ṣì ń mu ọmú, ó sun ún lódidi, ó fi rúbọ sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó gbadura sí OLUWA fún ìrànlọ́wọ́ Israẹli; OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀. Nígbà tí Samuẹli ń rúbọ lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, láti bá wọn jagun. Ṣugbọn OLUWA sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run wá. Ìdààmú bá wọn, wọ́n sì túká pẹlu ìpayà. Àwọn ọmọ Israẹli bá kó ogun jáde láti Misipa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ ogun Filistini lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìsàlẹ̀ Betikari, wọ́n ń pa wọ́n bí wọ́n ti ń lé wọn lọ. Samuẹli gbé òkúta kan, ó rì í mọ́lẹ̀ láàrin Misipa ati Ṣeni, ó sì sọ ibẹ̀ ni Ebeneseri, ó ní, “OLUWA ràn wá lọ́wọ́ títí dé ìhín yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹgun àwọn ará Filistia, wọn kò sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli mọ́. OLUWA n ṣe àwọn ará Filistia níbi ní gbogbo ọjọ́ ayé Samuẹli. Gbogbo ìlú tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, láti Ekironi títí dé Gati, ni wọ́n dá pada fún wọn. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ilẹ̀ wọn pada lọ́wọ́ àwọn ará Filistia. Alaafia wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará Amori. Samuẹli jẹ́ adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí tí ó fi kú. Lọdọọdun níí máa ń lọ yípo Bẹtẹli, Giligali, ati Misipa, láti ṣe ìdájọ́. Lẹ́yìn náà, yóo pada lọ sí ilé rẹ̀, ní Rama, nítorí pé a máa dájọ́ fún àwọn eniyan níbẹ̀ pẹlu. Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA.
I. Sam 7:2-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí OLúWA fi wà ní Kiriati-Jearimu. Gbogbo ilé Israẹli ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùnréré ẹkún sí OLúWA. Samuẹli sọ fún gbogbo ilé Israẹli pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ OLúWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì àti Aṣtoreti kí ẹ sì fi ara yín jì fún OLúWA kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini” Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli yẹra fún Baali àti Aṣtoreti, wọ́n sì sin OLúWA nìkan ṣoṣo. Nígbà náà ni, Samuẹli wí pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ sí Mispa, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ OLúWA.” Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mispa, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú OLúWA. Ní ọjọ́ náà, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí OLúWA.” Samuẹli sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Israẹli ní Mispa. Nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé àwọn Israẹli ti péjọ ní Mispa, àwọn aláṣẹ Filistini gòkè wá láti kọlù wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, Ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Filistini. Wọ́n sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe OLúWA Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini.” Nígbà náà ni Samuẹli mú ọ̀dọ́-àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí OLúWA. Ó sí ké pe OLúWA nítorí ilé Israẹli, OLúWA sì dá a lóhùn. Nígbà tí Samuẹli ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Filistini súnmọ́ tòsí láti bá Israẹli ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, OLúWA sán àrá ńlá lu àwọn Filistini, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọkùnrin Israẹli tú jáde láti Mispa. Wọ́n sì ń lépa àwọn Filistini, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Beti-Kari. Samuẹli mú òkúta kan ó sì fi lélẹ̀ láàrín Mispa àti Ṣeni, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ebeneseri, wí pé, “Ibí ni OLúWA ràn wá lọ́wọ́ dé.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Filistini, wọn kò sì wá sí agbègbè àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Ní gbogbo ìgbésí ayé Samuẹli, ọwọ́ OLúWA lòdì sí àwọn Filistini. Àwọn ìlú láti Ekroni dé Gati tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ Israẹli ni ó ti gbà padà fún Israẹli, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Filistini. Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàrín Israẹli àti àwọn Amori. Samuẹli tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lórí Israẹli. Ní ọjọ́ ayé e rẹ̀. Láti ọdún dé ọdún, ó lọ yíká láti Beteli dé Gilgali dé Mispa, ó sì ń ṣe ìdájọ́ Israẹli ní gbogbo ibi wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ó máa ń padà sí ilé rẹ̀ ní Rama, níbí tí ilé rẹ̀ wà, ó sì túnṣe ìdájọ́ Israẹli níbẹ̀, ó sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún OLúWA.