I. Sam 5:1-12

I. Sam 5:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN Filistini si gbe Apoti Ọlọrun, nwọn si mu u lati Ebeneseri wá si Aṣdodu. Nigbati awọn Filistini gbe apoti Ọlọrun, nwọn si gbe e wá si ile Dagoni, nwọn gbe e kà ilẹ li ẹba Dagoni. Nigbati awọn ara Aṣdodu ji li owurọ ọjọ keji, kiye si i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa. Nwọn si gbe Dagoni, nwọn si tun fi i si ipò rẹ̀. Nigbati nwọn ji li owurọ̀ ọjọ keji, kiyesi i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa; ati ori Dagoni ati atẹlẹ ọwọ́ rẹ̀ mejeji ke kuro li oju ọ̀na; Dagoni ṣa li o kù fun ara rẹ̀. Nitorina awọn alufa Dagoni, ati gbogbo awọn ti ima wá si ile Dagoni, kò si tẹ oju ọ̀na Dagoni ni Aṣdodu titi di oni. Ọwọ́ Oluwa si wuwo si ara Aṣdodu, o si pa wọn run, o si fi iyọdi pọn wọn loju, ani Aṣdodu ati agbegbe rẹ̀. Nigbati awọn enia Aṣdodu ri pe bẹ̃ li o ri, nwọn si wi pe, Apoti Ọlọrun Israeli kì yio ba wa gbe: nitoripe ọwọ́ rẹ̀ wuwo si wa, ati si Dagoni ọlọrun wa. Nwọn ranṣẹ nitorina, nwọn si pè gbogbo awọn ijoye Filistini sọdọ wọn, nwọn bere pe, Awa o ti ṣe apoti Ọlọrun Israeli si? Nwọn si dahun pe, Ẹ jẹ ki a gbe apoti Ọlọrun Israeli lọ si Gati. Nwọn si gbe apoti Ọlọrun Israeli na lọ sibẹ. O si ṣe pe, lẹhin igbati nwọn gbe e lọ tan, ọwọ́ Oluwa si wà si ilu na pẹlu iparun nla, o si pọn awọn enia ilu na loju, ati ọmọde ati agbà, nwọn ni iyọdi. Nitorina nwọn rán apoti Ọlọrun lọ si Ekronu. O si ṣe, bi apoti Ọlọrun ti de Ekronu, bẹ̃li awọn enia Ekronu kigbe wipe, nwọn gbe apoti Ọlọrun Israeli tọ̀ ni wá, lati pa wa, ati awọn enia wa. Bẹ̃ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pe gbogbo ijoye Filistini jọ, nwọn si wipe, Rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, ki ẹ si jẹ ki o tun pada lọ si ipò rẹ̀, ki o má ba pa wa, ati awọn enia wa: nitoriti ipaiya ikú ti wà ni gbogbo ilu na; ọwọ́ Ọlọrun si wuwo gidigidi ni ibẹ. Awọn ọmọkunrin ti kò kú ni a si fi iyọdi pọn loju: igbe ilu na si lọ soke ọrun.

I. Sam 5:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn tí àwọn ará Filistia gba àpótí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n gbé e láti Ebeneseri lọ sí Aṣidodu. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Dagoni, oriṣa wọn; wọ́n sì gbé e kalẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ère oriṣa náà. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, àwọn ará ìlú Aṣidodu rí i pé ère Dagoni ti ṣubú lulẹ̀. Wọ́n bá a tí ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA. Wọ́n bá gbé e dìde, wọ́n gbé e pada sí ààyè rẹ̀. Nígbà tí ó tún di òwúrọ̀ kutukutu wọ́n tún bá a tí ère náà tún ti ṣubú tí ó tún ti dojú bolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA, ati pé orí ati ọwọ́ rẹ̀ mejeeji ti gé kúrò, wọ́n wà nílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé títí di òní olónìí, àwọn babalóòṣà oriṣa Dagoni ati gbogbo àwọn tí wọ́n máa ń bọ ọ́ kò jẹ́ tẹ ẹnu ọ̀nà ilé oriṣa Dagoni tí ó wà ní ìlú Aṣidodu, dídá ni wọ́n máa ń dá a kọjá. OLUWA jẹ àwọn ará ìlú Aṣidodu níyà gidigidi, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ìyà tí ó fi jẹ wọ́n, ati àwọn tí wọn ń gbé agbègbè wọn ni pé gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún. Nígbà tí àwọn ará Aṣidodu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun Israẹli ni ó ń jẹ àwa ati Dagoni, oriṣa wa níyà. A kò lè jẹ́ kí àpótí Ọlọrun Israẹli yìí wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín mọ́ rárá.” Wọ́n bá ranṣẹ lọ pe àwọn ọba Filistini jọ, wọ́n sì bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí Ọlọrun Israẹli yìí?” Wọ́n dáhùn pé kí wọ́n gbé e lọ sí Gati; wọ́n bá gbé e lọ sibẹ. Ṣugbọn nígbà tí àpótí Ọlọrun náà dé Gati, OLUWA jẹ ìlú náà níyà, ó mú kí gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún ati àgbà ati èwe wọn, ó sì mú ìpayà bá gbogbo wọn. Wọ́n tún gbé àpótí Ọlọrun náà ranṣẹ sí ìlú Filistini mìíràn, tí wọn ń pè ní Ekironi. Ṣugbọn bí wọ́n ti gbé e dé Ekironi ni àwọn ará ìlú fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun Israẹli dé síhìn-ín, láti pa gbogbo wa run.” Wọ́n bá ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí Ọlọrun Israẹli pada sí ibi tí ẹ ti gbé e wá, kí ó má baà pa àwa ati ìdílé wá run.” Ìpayà ńlá ti bá gbogbo ìlú nítorí OLUWA ń jẹ wọ́n níyà gidigidi. Ara gbogbo àwọn tí kò kú ninu wọn kún fún kókó ọlọ́yún. Ariwo àwọn eniyan náà sì pọ̀ pupọ.

I. Sam 5:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Filistini ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebeneseri sí Aṣdodu. Nígbà tí àwọn Filistini gbé àpótí Ọlọ́run náà lọ sí tẹmpili Dagoni, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀bá Dagoni. Nígbà tí àwọn ará Aṣdodu jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dagoni ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí OLúWA, wọ́n sì gbé Dagoni, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dagoni ṣì wá, ó ṣubú ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu-ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù. Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dagoni tàbí àwọn mìíràn tí ó wọ inú tẹmpili Dagoni ní Aṣdodu fi ń tẹ orí ìloro ẹnu-ọ̀nà. Ọwọ́ OLúWA wúwo lára àwọn ènìyàn Aṣdodu àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Aṣdodu rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti Israẹli kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dagoni ọlọ́run wá.” Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Filistini jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli?” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ sí Gati.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ OLúWA sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn oníkókó. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ekroni. Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ekroni, àwọn ará Ekroni fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Filistini jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí ààyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú: ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn. Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run.