I. Sam 4:3
I. Sam 4:3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn enia si de budo, awọn agbà Israeli si wipe, Nitori kini Oluwa ṣe le wa loni niwaju awọn Filistini? Ẹ jẹ ki a mu apoti majẹmu Oluwa ti mbẹ ni Ṣilo sọdọ wa, pe, nigbati o ba de arin wa, ki o le gba wa kuro lọwọ awọn ọta wa.
Pín
Kà I. Sam 4I. Sam 4:3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”
Pín
Kà I. Sam 4I. Sam 4:3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbàgbà Israẹli sì béèrè pé, “Èéṣe ti OLúWA fi mú kí àwọn Filistini ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA láti Ṣilo wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”
Pín
Kà I. Sam 4