I. Sam 4:1-11
I. Sam 4:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Samueli si wá si gbogbo Israeli: Israeli si jade lọ pade awọn Filistini lati jagun, nwọn do si eti Ebeneseri: awọn Filistini si do ni Afeki. Awọn Filistini si tẹ itẹgun lati pade Israeli: nigbati nwọn pade ija, awọn Filistini si le Israeli: nwọn si pa iwọn ẹgbaji ọkunrin ni itẹgun ni papa. Awọn enia si de budo, awọn agbà Israeli si wipe, Nitori kini Oluwa ṣe le wa loni niwaju awọn Filistini? Ẹ jẹ ki a mu apoti majẹmu Oluwa ti mbẹ ni Ṣilo sọdọ wa, pe, nigbati o ba de arin wa, ki o le gba wa kuro lọwọ awọn ọta wa. Bẹli awọn enia si ranṣẹ si Ṣilo, pe ki nwọn gbe lati ibẹ wá apoti majẹmu Oluwa awọn ọmọ-ogun ẹniti o joko larin awọn kerubu: ati awọn ọmọ Eli mejeji, Hofni ati Finehasi, wà nibẹ pẹlu apoti majẹmu Ọlọrun. Nigbati apoti majẹmu Oluwa de budo, gbogbo Israeli si ho yè, tobẹ̃ ti ilẹ mì. Nigbati awọn Filistini si gbọ́ ohùn ariwo na, nwọn si wipe, Ohùn ariwo nla kili eyi ni budo awọn Heberu? O si wa ye wọn pe, apoti majẹmu Oluwa li o de budo. Ẹ̀ru si ba awọn Filistini, nwọn si wipe, Ọlọrun wọ budo. Nwọn si wipe, Awa gbe! nitoripe iru nkan bayi kò si ri. A gbe! tani yio gbà wa lọwọ Ọlọrun alagbara wọnyi? awọn wọnyi li Ọlọrun ti o fi gbogbo ipọnju pọn Egipti loju li aginju. Ẹ jẹ alagbara, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹnyin Filistini, ki ẹnyin máṣe ẹrú fun awọn Heberu, bi nwọn ti nṣe ẹrú nyin ri: Ẹ ṣe bi ọkunrin, ki ẹ si ja. Awọn Filistini si ja, nwọn si lé Israeli, nwọn si sa olukuluku sinu ago rẹ̀: ipani si pọ̀ gidigidi, awọn ẹlẹsẹ ti o ṣubu ninu ogun Israeli jẹ ẹgbãmẹdogun. Nwọn si gbà apoti ẹri Ọlọrun: ọmọ Eli mejeji si kú, Hofni ati Finehasi.
I. Sam 4:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli náà bá kó ogun jáde láti bá wọn jà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pàgọ́ sí Ebeneseri, àwọn ọmọ ogun Filistini sì pa tiwọn sí Afeki. Àwọn ọmọ ogun Filistini ni wọ́n kọ́ kọlu àwọn ọmọ ogun Israẹli, nígbà tí àwọn mejeeji gbógun pàdé ara wọn, tí wọ́n sì jà fitafita; àwọn ọmọ ogun Filistini ṣẹgun Israẹli, wọ́n sì pa nǹkan bíi ẹgbaaji (4,000) ninu wọn. Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí Ṣilo láti gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA tí ó gúnwà láàrin àwọn Kerubu. Àwọn ọmọ Eli mejeeji, Hofini ati Finehasi, sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà. Nígbà tí wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí dé ibùdó, gbogbo Israẹli hó ìhó ayọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì tìtì. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ híhó tí wọn ń hó, wọ́n ní, “Irú ariwo ńlá wo ni àwọn Heberu ń pa ní ibùdó wọn yìí?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àpótí ẹ̀rí OLUWA ni ó dé sí ibùdó àwọn Heberu, ẹ̀rù ba àwọn ará Filistia. Wọ́n ní, “Oriṣa kan ti dé sí ibùdó wọn! A gbé! Irú èyí kò ṣẹlẹ̀ rí. A gbé! Ta ni lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn oriṣa tí ó lágbára wọnyi? Àwọn ni wọ́n pa àwọn ará Ijipti ní ìpakúpa ninu aṣálẹ̀. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, ẹ̀yin ọmọ ogun Filistini! Ẹ ṣe bí akọni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óo di ẹrú àwọn ará Heberu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ẹrú wa, nítorí náà, ẹ ṣe bí akọni, kí ẹ sì jà.” Àwọn ọmọ ogun Filistini jà fitafita, wọ́n ṣẹgun Israẹli, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli sì sá pada lọ sí ilé rẹ̀, ọpọlọpọ ló kú ninu wọn. Ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000) ni ọmọ ogun Filistini pa ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ń fi ẹsẹ̀ rìn. Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli mejeeji.
I. Sam 4:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ Samuẹli tọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá. Nísinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli jáde láti lọ bá àwọn Filistini jà. Àwọn ọmọ Israẹli sì pàgọ́ sí Ebeneseri àti àwọn Filistini ní Afeki. Àwọn Filistini mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Israẹli, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Filistini ṣẹ́gun Israẹli wọ́n pa ẹgbàajì ọkùnrin nínú ogun náà (4,000). Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbàgbà Israẹli sì béèrè pé, “Èéṣe ti OLúWA fi mú kí àwọn Filistini ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA láti Ṣilo wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣilo, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wá, ẹni tí ń wà láàrín àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Eli méjèèjì Hofini àti Finehasi wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Nígbà tí àpótí ẹ̀rí OLúWA wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì. Ní ìgbà tí àwọn Filistini gbọ́ ariwo náà wọ́n béèrè pé, “Kí ni gbogbo ariwo yìí ní ibùdó Heberu?” Nígbà tí wọ́n mọ̀ wí pé àpótí ẹ̀rí OLúWA ti wá sí ibùdó, Àwọn Filistini sì bẹ̀rù pé, Ọlọ́run kékeré ti wọ ibùdó, wọ́n wí pé, “A wọ wàhálà, irú èyí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí. Àwa gbé! Ta ni yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run alágbára yìí? Àwọn ni Ọlọ́run tí ó fi ìpọ́njú pa àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo àjàkálẹ̀-ààrùn ní aginjù. Ẹ jẹ́ alágbára Filistini, ẹ ṣe bí ọkùnrin, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin yóò di ẹrú àwọn Heberu, bí wọ́n ti jẹ́ sí i yín: Ẹ jẹ́ alágbára ọkùnrin, kí ẹ sì jagun!” Nígbà náà àwọn Filistini jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Israẹli olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn; Àwọn ará Israẹli tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́dógún àwọn ọmọ-ogun orí ilẹ̀ (30,000). Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí OLúWA, àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì sì kú, Hofini àti Finehasi.