I. Sam 3:7-19
I. Sam 3:7-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Samueli ko iti mọ̀ Oluwa, bẹ̃ni a ko iti fi ọ̀rọ Oluwa hàn a. Oluwa si tun Samueli pè lẹ̃kẹta. O si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi niyi; nitori iwọ pè mi. Eli, si mọ̀ pe, Oluwa li o npe ọmọ na. Nitorina Eli wi fun Samueli pe, Lọ dubulẹ: yio si ṣe, bi o ba pè ọ, ki iwọ si wipe, ma wi, Oluwa; nitoriti iranṣẹ rẹ ngbọ́. Bẹ̃ni Samueli lọ, o si dubulẹ nipò tirẹ̀. Oluwa wá, o si duro, o si pè bi igbá ti o kọja, Samueli, Samueli. Nigbana ni Samueli dahun pè, Ma wi; nitori ti iranṣẹ rẹ ngbọ́. Oluwa si wi fun Samueli pe, Kiyesi i, emi o ṣe ohun kan ni Israeli, eyi ti yio mu eti mejeji olukuluku awọn ti o gbọ́ ọ ho. Li ọjọ na li emi o mu gbogbo ohun ti mo ti sọ si ile Eli ṣẹ: nigbati mo ba bẹrẹ, emi o si ṣe e de opin. Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun. Nitorina emi ti bura si ile Eli, pe ìwa-buburu ile Eli li a kì yio fi ẹbọ tabi ọrẹ wẹ̀nù lailai. Samueli dubulẹ titi di owurọ, o si ṣi ilẹkun ile OLUWA. Samueli si bẹru lati rò ifihan na fun Eli. Nigbana ni Eli pe Samueli, o si wipe, Samueli, ọmọ mi. On si dahun pe, Emi nĩ. O si wipe, Kili ohun na ti Oluwa sọ fun ọ? emi bẹ ọ máṣe pa a mọ fun mi: ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si ọ, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ ba pa ohun kan mọ fun mi ninu gbogbo ohun ti o sọ fun ọ. Samueli si rò gbogbo ọ̀rọ na fun u, kò si pa ohun kan mọ fun u. O si wipe, Oluwa ni: jẹ ki o ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀. Samueli ndagba, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀, kò si jẹ ki ọkan ninu ọ̀rọ rẹ̀ wọnni bọ́ silẹ.
I. Sam 3:7-19 Yoruba Bible (YCE)
Samuẹli kò mọ̀ pé OLUWA ni, nítorí OLUWA kò tíì bá a sọ̀rọ̀ rí. OLUWA pe Samuẹli nígbà kẹta, ó bá tún dìde, ó tọ Eli lọ, ó ní “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli wá mọ̀ nígbà náà pé, OLUWA ni ó ń pe ọmọ náà. Ó bá wí fún un pé, “Pada lọ sùn. Bí olúwarẹ̀ bá tún pè ọ́, dá a lóhùn pé, ‘Máa wí OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.’ ” Samuẹli bá pada lọ sùn. OLUWA tún wá, ó dúró níbẹ̀, ó pe Samuẹli bí ó ti pè é tẹ́lẹ̀, ó ní “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli bá dáhùn pé, “Máa wí, OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.” OLUWA bá sọ fún un pé, “Mo múra tán láti ṣe nǹkankan ní Israẹli, ohun tí mo fẹ́ ṣe náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí yóo ya ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ lẹ́nu. Ní ọjọ́ náà, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ pé n óo ṣe sí ìdílé Eli, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Mo ti sọ fún un pé n óo jẹ ìdílé rẹ̀ níyà títí lae, nítorí pé àwọn ọmọ rẹ̀ ti ṣe nǹkan burúkú sí mi. Eli mọ̀ pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lẹ́kun. Nítorí náà, mo ti búra fún ilé Eli pé, kò sí ẹbọ kan tabi ọrẹ tí ó lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú náà kúrò laelae.” Samuẹli dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó dìde, ó ṣí gbogbo ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ṣugbọn ẹ̀rù ń bà á láti sọ ìran tí ó rí fún Eli. Eli pè é, ó ní, “Samuẹli, ọmọ mi!” Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.” Eli bi í pé, “Kí ni OLUWA wí fún ọ, má fi nǹkankan pamọ́ fún mi. OLUWA yóo ṣe sí ọ jù bí ó ti sọ fún ọ lọ, bí o bá fi nǹkankan pamọ́ fún mi ninu ohun tí ó sọ fún ọ.” Samuẹli bá sọ gbogbo rẹ̀ patapata, kò fi nǹkankan pamọ́ fún un. Eli dáhùn pé, “OLUWA ni, jẹ́ kí ó ṣe bí ó bá ti tọ́ lójú rẹ̀.” Samuẹli sì ń dàgbà, OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ṣẹ.
I. Sam 3:7-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ OLúWA: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ OLúWA hàn án. OLúWA pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.” Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé OLúWA ni ó ń pe ọmọ náà. Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘máa wí, OLúWA nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀. OLúWA wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!” Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.” OLúWA sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro. Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun. Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ” Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé OLúWA, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli. Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.” Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.” Eli béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.” Samuẹli sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Eli wí pé, “Òun ni OLúWA; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.” OLúWA wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà.