I. Sam 29:1-11

I. Sam 29:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ará Filistia kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ sí Afeki, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì pa ibùdó sí etí orísun omi tí ó wà ní àfonífojì Jesireeli. Bí àwọn ọba Filistini ti ń kọjá pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn ní ọgọọgọrun-un ati ẹgbẹẹgbẹrun, Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ tò sẹ́yìn ọba Akiṣi. Àwọn olórí ogun Filistini bèèrè pé, “Kí ni àwọn Heberu wọnyi ń ṣe níbí?” Akiṣi sì dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí Dafidi, iranṣẹ Saulu ọba Israẹli nìyí, ó ti wà lọ́dọ̀ mi láti ìgbà pípẹ́, n kò tíì rí àṣìṣe kan lọ́wọ́ rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.” Àwọn olórí ogun náà bínú sí i gidigidi, wọ́n ní, “Sọ fún un, kí ó pada síbi tí o fún un, kí ó má bá wa lọ sójú ogun, kí ó má baà dojú ìjà kọ wá. Kí ni ìwọ rò pé yóo fẹ́ fi bá oluwa rẹ̀ làjà? Ṣebí nípa pípa àwọn ọmọ ogun wa ni. Àbí nítorí Dafidi yìí kọ́ ni àwọn ọmọbinrin Israẹli ṣe ń jó tí wọ́n sì ń kọrin pé, ‘Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀, ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ” Akiṣi pe Dafidi, ó sọ fún un pé, “Mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí pé o jẹ́ olóòótọ́ sí mi, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá mi lọ sójú ogun yìí, nítorí pé n kò tíì rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ rẹ láti ìgbà tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní. Ṣugbọn àwọn olórí ogun kò gbà pé kí o bá wa lọ. Nítorí náà, jọ̀wọ́ pada ní alaafia, kí o má baà múnú bí wọn.” Dafidi dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ìdí rẹ̀ tí n kò fi ní lè lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jà, nígbà tí o kò rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ mi láti ìgbà tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?” Akiṣi sì dáhùn pé, “Nítòótọ́ ni, mo mọ̀ pé o jẹ́ ẹni rere bí angẹli OLUWA, ṣugbọn àwọn olórí ogun ti sọ pé, o kò lè bá wa lọ sójú ogun. Nítorí náà, dìde ní òwúrọ̀, ìwọ ati àwọn iranṣẹ oluwa rẹ, tí wọ́n bá ọ wá, kí ẹ sì máa lọ ní kété tí ilẹ̀ bá ti mọ́.” Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá dìde, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Filistini, àwọn ọmọ ogun Filistini sì lọ sí Jesireeli.

I. Sam 29:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn Filistini sì kó gbogbo ogun wọn jọ sí Afeki: Israẹli sì dó ni ibi ìsun omi tí ó wà ní Jesreeli. Àwọn ìjòyè Filistini sì kọjá ní ọ̀rọ̀ọ̀rún àti lẹ́gbẹgbẹ̀rún; Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Akiṣi sì kẹ́yìn. Àwọn ìjòyè Filistini sì béèrè wí pé, “Kín ni àwọn Heberu ń ṣe níhìn-ín yìí?” Akiṣi sì wí fún àwọn ìjòyè Filistini pé “Dafidi kọ yìí, ìránṣẹ́ Saulu ọba Israẹli, tí ó wà lọ́dọ̀ mi láti ọjọ́ wọ̀nyí tàbí láti ọdún wọ̀nyí, èmi kò ì tì í rí àṣìṣe kan ni ọwọ́ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.” Àwọn ìjòyè Filistini sì bínú sí i; àwọn ìjòyè Filistini sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí ọkùnrin yìí padà kí ó sì lọ sí ipò rẹ̀ tí ó fi fún un, kí ó má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ogun, kí ó má ba à jásí ọ̀tá fún wa ni ogun; Kín ni òun ó fi ba olúwa rẹ̀ làjà, orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́? Ṣé èyí ni Dafidi tiwọn torí rẹ̀ gberin ara wọn nínú ijó wí pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹgbẹ̀rún rẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbàarùn-ún tirẹ̀.’ ” Akiṣi sì pe Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Bí OLúWA ti ń bẹ láààyè, ìwọ jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tí ì ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́. Ǹjẹ́ yípadà kí o sì máa lọ ní àlàáfíà, kí ìwọ má ṣe bà àwọn Filistini nínú jẹ́.” Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Kín ni èmi ṣe? Kín ni ìwọ sì rí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ ti èmi ti ń gbé níwájú rẹ títí di òní yìí, tí èmi kì yóò fi lọ bá àwọn ọ̀tá ọba jà.” Akiṣi sì dáhùn, ó sì wí fún Dafidi pé, “Èmi mọ̀ pé ìwọ ṣe ẹni rere lójú mi, bi angẹli Ọlọ́run; ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Filistini wí pé, Òun kì yóò bá wa lọ sí ogun. Ǹjẹ́, nísinsin yìí dìde ní òwúrọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ tí ó bá ọ wá: ki ẹ si dìde ní òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́ kí ẹ sì máa lọ.” Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì dìde ní òwúrọ̀ láti padà lọ sí ilẹ̀ àwọn Filistini. Àwọn Filistini sì gòkè lọ sí Jesreeli.

I. Sam 29:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN Filistini si ko gbogbo ogun wọn jọ si Afeki: Israeli si do ni ibi isun omi ti o wà ni Jesreeli. Awọn ijoye Filistini si kọja li ọrọrun ati li ẹgbẹgbẹrun; Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pẹlu Akiṣi si kẹhin. Awọn ijoye Filistini si bere wipe, Kini awọn Heberu nṣe nihinyi? Akiṣi si wi fun awọn ijoye Filistini pe, Dafidi kọ yi, iranṣẹ Saulu ọba Israeli, ti o wà lọdọ mi lati ọjọ wọnyi tabi lati ọdun wọnyi, emi ko iti ri iṣiṣe kan li ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ ti o ti de ọdọ mi titi di oni yi. Awọn ijoye Filistini si binu si i; awọn ijoye Filistini si wi fun u pe, jẹ ki ọkunrin yi pada ki o si lọ si ipò rẹ̀ ti o fi fun u, ki o má si jẹ ki o ba wa sọkalẹ lọ si ogun, ki o má ba jasi ọta fun wa li ogun; Kini on o fi ba oluwa rẹ̀ laja, ori awọn enia wọnyi kọ? Ṣe eyi ni Dafidi ti nwọn tori rẹ̀ gberin ara wọn ninu ijo wipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbãrun tirẹ̀? Akiṣi si pe Dafidi, o si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, iwọ jẹ olõtọ ati ẹni ìwa rere loju mi, ni alọ rẹ ati abọ̀ rẹ pẹlu mi li ogun; nitoripe emi ko iti ri buburu kan lọwọ rẹ lati ọjọ ti iwọ ti tọ̀ mi wá, titi o fi di oni yi: ṣugbọn loju awọn ijoye iwọ kò ṣe ẹni ti o tọ́. Njẹ yipada ki o si ma lọ li alafia, ki iwọ ki o má ba ṣe ibanujẹ fun awọn Filistini. Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Kili emi ṣe? kini iwọ si ri lọwọ iranṣẹ rẹ lati ọjọ ti emi ti gbe niwaju rẹ titi di oni yi, ti emi kì yio fi lọ ba awọn ọta ọba ja? Akiṣi si dahun o si wi fun Dafidi pe, Emi mọ̀ pe iwọ ṣe ẹni-rere loju mi, bi angeli Ọlọrun: ṣugbọn awọn ijoye Filistini wi pe, On kì yio ba wa lọ si ogun. Njẹ, nisisiyi dide li owurọ pẹlu awọn iranṣẹ oluwa rẹ ti o ba ọ wá: ki ẹ si dide li owurọ nigbati ilẹ ba mọ́, ki ẹ si ma lọ. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si dide li owurọ lati pada lọ si ilẹ awọn Filistini. Awọn Filistini si goke lọ si Jesreeli.