I. Sam 26:1-4
I. Sam 26:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ara Sifi si tọ̀ Saulu wá si Gibea, nwọn wipe, Ṣe Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ nibi oke Hakila, eyi ti o wà niwaju Jeṣimoni? Saulu si dide o si sọkalẹ lọ si ijù Sifi, ẹgbẹ̀dogun àṣayàn enia ni Israeli si pẹlu rẹ̀ lati wá Dafidi ni iju Sifi. Saulu si pagọ rẹ̀ ni ibi oke Hakila ti o wà niwaju Jeṣimoni li oju ọ̀na. Dafidi si joko ni ibi iju na, o si ri pe Saulu ntẹle on ni iju na. Dafidi si ran amí jade, o si mọ̀ nitõtọ pe Saulu mbọ̀.
I. Sam 26:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọkunrin kan, ará Sifi lọ sọ fún Saulu ní Gibea pé, “Dafidi farapamọ́ sí òkè Hakila tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jeṣimoni.” Lẹsẹkẹsẹ, Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ wá Dafidi ninu aṣálẹ̀ Sifi. Wọ́n pabùdó wọn sí ẹ̀bá ọ̀nà ní òkè Hakila, Dafidi sì wà ninu aṣálẹ̀ náà. Nígbà tí Dafidi mọ̀ pé Saulu ń wá òun kiri, ó rán amí láti rí i dájú pé Saulu wà níbẹ̀.
I. Sam 26:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni àwọn ará Sifi tọ Saulu wá sí Gibeah, wọn wí pé, “Dafidi kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hakila, èyí tí ó wà níwájú Jeṣimoni?” Saulu sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sifi ẹgbẹ̀ẹ́dógún àṣàyàn ènìyàn ni Israẹli sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dafidi ni ijù Sifi. Saulu sì pàgọ́ rẹ̀ ní ibi òkè Hakila tí o wà níwájú Jeṣimoni lójú ọ̀nà, Dafidi sì jókòó ni ibi ijù náà, ó sì rí pé Saulu ń tẹ̀lé òun ni ijù náà. Dafidi sì rán ayọ́lẹ̀wò jáde, ó sì mọ nítòótọ́ pé Saulu ń bọ̀.