I. Sam 24:6-7
I. Sam 24:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni. Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.
I. Sam 24:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Ó sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Kí OLUWA pa mí mọ́ kúrò ninu ṣíṣe ibi sí oluwa mi, ẹni tí OLUWA ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọba. N kò gbọdọ̀ fọwọ́ mi kàn án, nítorí ẹni àmì òróró OLUWA ni.” Nípa báyìí Dafidi dá àwọn eniyan rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọ́n pa Saulu. Saulu jáde ninu ihò náà, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.
I. Sam 24:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ OLúWA wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi ààmì òróró OLúWA yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni ààmì òróró OLúWA ni.” Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.