I. Sam 22:1-5
I. Sam 22:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si kuro nibẹ, o si sa si iho Adullamu; nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ati idile baba rẹ̀ si gbọ́ ọ, nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ nibẹ. Olukuluku ẹniti o ti wà ninu ipọnju, ati olukuluku ẹniti o ti jẹ gbesè, ati olukuluku ẹniti o wà ninu ibanujẹ, si ko ara wọn jọ sọdọ rẹ̀, on si jẹ olori wọn: awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ si to iwọn irinwo ọmọkunrin. Dafidi si ti ibẹ̀ na lọ si Mispe ti Moabu: on si wi fun ọba Moabu pe, Jẹ ki baba ati iya mi, emi bẹ̀ ọ, wá ba ọ gbe, titi emi o fi mọ̀ ohun ti Ọlọrun yio ṣe fun mi. O si mu wọn wá siwaju ọba Moabu; nwọn si ba a gbe ni gbogbo ọjọ ti Dafidi fi wà ninu ihò na. Gadi woli si wi fun Dafidi pe, Máṣe gbe inu ihò na; yẹra, ki o si lọ si ilẹ Juda. Nigbana ni Dafidi si yẹra, o si lọ sinu igbo Hareti.
I. Sam 22:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi sá kúrò ní ìlú Gati, lọ sinu ihò òkúta kan lẹ́bàá Adulamu. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀ gbọ́, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, ati àwọn tí wọ́n jẹ gbèsè ati àwọn tí wọ́n wà ninu ìbànújẹ́ sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400) ọkunrin, ó sì jẹ́ olórí wọn. Dafidi kúrò níbẹ̀ lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Moabu, ó sọ fún ọba Moabu pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí baba ati ìyá mi dúró lọ́dọ̀ rẹ títí tí n óo fi mọ ohun tí Ọlọrun yóo ṣe fún mi.” Dafidi fi àwọn òbí rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ọba Moabu, wọ́n sì wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Dafidi wà ní ìpamọ́. Wolii Gadi sọ fún Dafidi pé, “Má dúró níbi ìpamọ́ yìí mọ́, múra, kí o lọ sí ilẹ̀ Juda.” Dafidi bá lọ sí igbó Hereti.
I. Sam 22:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Adullamu; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀. Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irínwó ọmọkùnrin. Dafidi sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mispa tí Moabu: ó sì wí fún ọba Moabu pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.” Ó sì mú wọn wá síwájú ọba Moabu; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dafidi fi wà nínú ihò náà. Gadi wòlíì sí wí fún Dafidi pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Juda.” Nígbà náà ni Dafidi sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hereti.