I. Sam 21:1-2
I. Sam 21:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si wá si Nobu sọdọ Ahimeleki alufa; Ahimeleki si bẹ̀ru lati pade Dafidi, o si wi fun u pe, Eha ti ri ti o fi ṣe iwọ nikan, ati ti kò si fi si ọkunrin kan ti o pẹlu rẹ? Dafidi si wi fun Ahimeleki alufa pe, ọba paṣẹ iṣẹ kan fun mi, o si wi fun mi pe, Máṣe jẹ ki ẹnikan mọ̀ idi iṣẹ na ti mo rán ọ, ati eyi ti emi ti paṣẹ fun ọ; emi si yàn awọn iranṣẹ mi si ibi bayi.
I. Sam 21:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki alufaa, ní Nobu. Ahimeleki sì jáde pẹlu ìbẹ̀rù láti pàdé rẹ̀, ó sì bi í pé, “Ṣé kò sí nǹkan tí ìwọ nìkan fi dá wá, tí kò sí ẹnikẹ́ni pẹlu rẹ?” Ó dáhùn pé, “Ọba ni ó rán mi ní iṣẹ́ pataki kan, ó sì ti sọ fún mi pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ tí òun rán mi. Mo sì ti sọ fún àwọn iranṣẹ mi pé kí wọ́n pàdé mi ní ibìkan.
I. Sam 21:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?” Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí.